NNKAN DE! ISINKU AJIMỌBI TUN DA WAHALA NLA SILẸ N'IBADAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 27, 2020

NNKAN DE! ISINKU AJIMỌBI TUN DA WAHALA NLA SILẸ N'IBADAN

Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe ko ti i daju wi pe wọn yoo sinku Gomina ana n'ipinlẹ ọyọ, Abiọla Isiaka Ajimọ to d'oloogbe l'Ọjọbọ, iyẹn Tọside ọsẹ to kọja yii pẹlu bi wọn ṣe sọ pe eto isinku rẹ ti da wahala rẹpẹtẹ silẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ wọn ni ija awọn ti yoo sinku ọkunrin naa lo kọkọ ti n da wahala abẹle silẹ laaarin iyawo Ajimọbi, Arabinrin Florence Ajimọbi at'awọn mọlẹbi ọkọ rẹ.

AWIKONKO gbọ pe Arabinrin Florence ti sọ pe oun ko le gba k'awọn ẹlẹsin musulumi sinku ọkọ oun, ṣugbọn ti wọn l'awọn mọlẹbi sọ pe ọrọ rẹ ko le ṣẹ.

F'awọn to ba mọ obinrin naa daadaa, wọn yoo mọ pe ẹsin Kristẹni l'oun n ṣe ni tirẹ, ti ọkọ rẹ si jẹ Alaaji, koda, to tun kọ mọṣalaṣi rẹpẹtẹ f'awọn ẹlẹsin musulumi,

Wọn ni ọrọ naa ti ni iyanju l'ọjọ Ẹti, Fraide ana, ti wọn si ni gbogbo ẹbi ti fẹnuko lati gba pe ki wọn sin oloogbe naa n'ilana musulumi, ti wọn si fẹnuko lati sinku rẹ laarọ oni, Abamẹta, Satide.

Atẹjade ti wọn ni amugbalẹgbẹ Ajimọbi lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Bọlaji tunji fi sita l'ọjọ Ẹti ana wi pe mọṣalaṣi kan ti Ajimọbi kọ si Oke-Ado n'ilu Ibadan, iyẹn Abiola Ajimobi Central Mosque ni wọn yoo sinku rẹ si laago mejila ọsan ọjọ Aiku, iyẹn Sande ọla, gẹgẹ bi ipade t'awọn mọlẹbi ṣe, ti wọn si f'ẹnu ko si.

Eyi ni wọn loo tun da wahala nla silẹ, n'igba ti wọn sọ pe awọn kan ko gba lati fẹ ki wọn sinku rẹ sibẹ, wọn l'awọn kan ti wọn ko n'ifẹ ọkunrin naa ni wọn dide lati tako o pe awọn ko ni i gba ki wọn sin in sibẹ.

Wọn ni ki wọn gbe oku rẹ lọ s'itẹku, tabi ki wọn lọ sin in si ọkan lara awọn ile to kọ kaakiri. Titi di asiko ti a kọ iroyin yii tan ni wọn ṣi wa lénu wahala naa.

Bi nnkan ba ṣe ri la maa mu u wa fun un yin laipẹ. Ẹ ku ojulọna

bayii, ni wọn tun ṣe sọ pe ibi ti wọn fẹẹ sin in si

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI