ASIKO TA A NILO AJIMỌBI LO KU YI O - ẸGBẸ OṢELU APC BANUJẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 26, 2020

ASIKO TA A NILO AJIMỌBI LO KU YI O - ẸGBẸ OṢELU APC BANUJẸ

Ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹ-ede Naijiria ti sọ pe asiko t'awọn nilo gomina ana n'ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Isiaka Abiọla Ajimọbi lo dagbere faye.
Bẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni ẹgbẹ APC kede Ajimọbi gẹgẹ bi alaga fidihẹ ẹgbẹ naa lẹyin ti ile-ẹjọ kotẹmilọrun le Adams Ọṣhiọmhọlẹ danu.

Loni ọjọ Ẹti, Fraide ni alaga igbimọ amuṣẹṣe lapapọ, Mai Mala Buni sọrọ naa pẹlu ibanujẹ ọkan.
Buni to tun jẹ Gomina ipinlẹ Yobe gba ipo naa l'Ọjọbọ, Tọside ana.

O ni "Ajimọbi ku lasiko ti a nilo rẹ gidi, iyẹn lasiko ti a n wa awọn adari gidi ti yoo di ẹgbẹ naa mu, eyi ti yoo jẹ ki atunṣe de ba ẹgbẹ naa."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI