O MA ṢE O! Ẹ TUN WO BABA ARUGBO T'AWỌN FULANI DARANDARAN ṢA PA SINU OKO RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 16, 2020

O MA ṢE O! Ẹ TUN WO BABA ARUGBO T'AWỌN FULANI DARANDARAN ṢA PA SINU OKO RẸ


Iṣẹlẹ naa gba omi pupọ loju awọn eeyan, paapaa awọn to ri oku baba arugbo kan, Mazi Ozoemena Iriaka, ẹni ọdun marundinlaadọrin (65) ti wọn l'awọn Fulani darandaran ṣa pa sinu oko rẹ l'ọjọ Aiku, iyẹn Sande ijẹta.

Ni kete to pe wakati mejidinlaadọta (48hours) ti Aarẹ Muhammadu Buhari kede wi pe awọn ti ṣẹgun iṣekupaniyan lorilẹ-ede Naijiria, ati pe awọn ti ṣe atunṣe lori b'awọn Fulani darandaran ṣe n ṣiṣẹ wọn, iyẹn bi wọn ṣe n ko maluu kaakiri lati jẹ'ko l'awọn darandaran naa pa baba arugbo yii.

 
Agbegbe Umuekpu-Agwa, to wa n'ijọba ibilẹ Oguta, ipinlẹ Imo n'iṣẹlẹ naa ti waye.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn ara agbegbe naa ni wọn gburo wi pe awọn darandaran yii ti de agbegbe wọn, wọn si ti n fi maluu wọn je gbogbo oko ti wọn da, lilọ ti wọn ko ara wọn lọ ni lati b'awọn sọrọ asọyepọ.

Ṣugbọn iyalẹnu ni wọn loo jẹ nigba ti wọn debẹ, ti wọn si ni ṣe l'awọn darandaran yii yọ ibọn AK47 si wọn pẹlu ada, eyi to mu ki gbogbo na papa bora.

Baba agbalagba yii n'ikan la gbọ pe wọn ri mu, ti wọn si ṣaa niṣakuṣa titi ti wọn fi gba ẹmi ẹ.

 
Awọn ara agbegbe naa ti wọn sọrọ sọ pe iṣẹlẹ yii ko ṣẹṣẹ maa waye lagbegbe naa, ti wọn si ni ṣe l'awọn Fulani darandaran naa maa n dunkooko mọ awọn, ti wọn yoo si tun fi maluu wọn jẹ gbogbo ire oko wọn.

Wọn ni lati ọdun 2015 ti Aarẹ Buhari ti wọle l'awọn ti n koju wahala yii, ti ko si sẹni ti yoo gba wọn, lẹyin t'awọn ti ke gbajare s'ijọba ipinlẹ naa ati ti Naijiria lapapọ. 

Awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn pada waa gbe oku baba naa kuro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI