ANGẸLI AGABAGEBE NI ṢODIYAN JẸ, KO SI NINU ẸGBẸ FIJILANTE N'IPINLẸ OGUN, IRỌ LO N PA KAAKIRI - ADEDOYIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 30, 2020

ANGẸLI AGABAGEBE NI ṢODIYAN JẸ, KO SI NINU ẸGBẸ FIJILANTE N'IPINLẸ OGUN, IRỌ LO N PA KAAKIRI - ADEDOYIN


Kọmanda Adedoyin sọ pe ipo ni Ṣodiyan n wa kaakiri ninu ijọba ipinlẹ Ogun, ati pe anfaani wi pe oun ati Gomina Dapọ Abiọdun wa lati ijọba ibilẹ kan naa lo fẹ maa lo lati gbajumọ, to si ni ọrọ rẹ dabi ẹṣin inu iwe ti ko le lọ sibi kankan.

Laipẹ yii ni awọn iroyin ayelujara meji kan gbe iroyin sita nipa ifọrọwerọ ti wọn ba Ṣọdiyan ti wọn le danu kuro ninu ẹgbẹ Fijilante ni nnkan bi ọdun meji sẹyin lori ẹsun aṣemaṣe ẹẹmẹta ọtọọtọ ti fi kan an, ninu ifọrọwerọ naa lo ti bu ẹnu atẹ lu Kọmanda Adedoyin, Oluṣọla Ọlawale at'awọn kan ninu VGN.

N'igba to n b'AWIKONKO sọrọ ninu ọfiisi rẹ to wa nilu Abẹokuta l'Ọjọru, Wẹside ana lati tako awọn ẹsun naa, Kọmanda Nureni Adedoyin sọ pe ko si nnkan meji tóun ri ninu irọ ti Ṣọla Ṣodiyan n gbe kaakiri, bi ko ṣe pe ipo lo n wa ninu ijọba Dapọ Abiọdun.

Adedoyin sọ pe "N'igba ti mo ka iroyin naa, mo ri i pe gbogbo ọrọ ti Ṣodiyan sọ patapata ni ko si otitọ kankan nibẹ rara, ṣe lo n gbiyanju lati ṣi awọn araalu ti ko mọ bi ọrọ ṣe jẹ lọkan.

"Lati ma jẹ ki awọn araalu tẹle irọ to n pa kaakiri, lo mu ki n fẹẹ sọrọ lati jẹ k'awọn eeyan mọ bo ṣe n lọ. Awọn ọga agba patapata ninu ẹgbẹ Fijilante lorilẹ-ede Naijiria ni wọn yan mi s'ipo yii l'ọdun 2016 lati maa ṣakoso eto aabo nípinlẹ Ogun, ti mi o si fi igba kankan ṣe aṣiṣe pẹlu oore-ọfẹ Ọlọrun.

"Mo fẹẹ fi da gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ loju wi pe Ṣọla Ṣodiyan ko si ninu ẹgbẹ VGN mọ tipẹtipẹ. O ti gba iwe ẹsun lẹẹmẹta ọtọọtọ, n'igba to si mọ pe lẹyin ẹsun ẹlẹẹkẹta, o di dandan ki wọn daa duro lẹnu iṣẹ fungba diẹ, eyi lo mu ko sa kuro.

"Ko yọju s'awọn ipade wa mọ, a ko ri i, ko da si nnkankan n'ipa eto aabo tabi VGN mọ. Ko si pẹlu wa mọ rara tipẹtipẹ, mi o wa mọ ipo rẹ ninu VGN to fi n lọ b'awọn oniroyin sọrọ kaakiri. Awọn to ba wa n'ipo aṣẹ nikan ni wọn lanfaani lati ba oniroyin sọrọ n'igba to ba yẹ, ki i ṣe ẹni ti ko ba si n'ipo depodepo wi pe ko si ninu ẹgbẹ wa.

"Ko di ipo kankan mu ri to fi kuro ninu ẹgbẹ VGN, o wa n sọrọ nipa Fijilante tuntun (Harmonized VGN), emi ki i b'awọn ṣe nnkan ti ko ba tẹle ofin gẹgẹ bi mo ṣe kẹkọọ gboye n'ipa eto aabo. Ẹ ranti n'igba ti wọn fẹ bẹrẹ VSO n'igba yẹn, mo ni lati yago kuro nibẹ nitori pe mi o fọwọ si i. Mi o ki i ṣe ẹgbẹ ti ko ba lorukọ pẹlu ileeṣẹ to n forukọ silẹ ni Naijiria, iyẹn Corporate Affairs Comission, CAC.

"Ko si nnkan to n jẹ Fijilante tuntun, Fijilante kan ṣoṣo to wa lo ni orukọ pẹlu CAC, iyẹn Vigilante Group of Nigeria. Gbogbo orukọ Fijilante to ba yatọ si VGN, ayederu ni wọn, nitori pe ẹ ko le rii ninu iwe-ẹri ti CAC fun wa.

"Mo ti lọ kaakiri awọn orilẹ-ede lati kẹkọọ nipa iṣẹ eto aabo, bawo ni maa ṣe wa a lọ darapọ mọ ẹgbẹ aabo ti ko lorukọ? ko ṣeeṣe.

"Mi o mọ idi to fi n sọrọ nipa ipade ti oludamọran pataki fun gomina ipinlẹ Ogun lori eto aabo ba wa ṣe, nitori pe ipade naa ko ni nnkan ṣe pẹlu Ṣodiyan rara. Lori ọrọ eto aabo Amọtẹkun nikan AIG Oluṣọla Subair ba wa ṣepade le lori lọjọ naa, ko si nnkan to n jẹ Harmonized VGN.

"Ki i ṣe irọ ni pe a ni igun meji ninu ẹgbẹ VGN, ti a ba fẹẹ darapọ di ẹyọkan, a ni iwe ofin wa digbi to le tọ wa sọna, a si dupẹ pe awọn ti igun keji ti n darapọ mọ wa. Mi o ba ẹnikankan ṣe ipade lori nnkan to n jẹ Harmonized VGN, irọ lasan lo wa nibẹ.

"Ti m ba fẹẹ ba ẹnikẹni ṣe ipade, ki i ṣe iru ẹni to ti fi ẹgbẹ wa silẹ, ti ko si ni nnkankan ṣe pẹlu wa. Ẹnikẹni lo le ṣiṣẹ eto aabo, ṣugbọn awa ti a ni itara fun un ko ni i gba ki madaru wọ aarin wa. Bẹẹ la si maa ri i daju pe a le awọn epo to wa ninu alikama wa danu lati le fọ VGN mọ kaakiri Naijiria, paapaa n'ipinlẹ Ogun.

"Oriṣiriṣi awọọdu ni mo ti gba kaakiri nipa iṣẹ eto aabo to peye, ti mi o ba ṣe daadaa, wọn ko ni i fun mi ni awọọdu, mi o si fi owo gba awọọdu. Ko sẹni to gba owo lọwọ mi ki wọn to fun mi lawọọdu.

"Ipo ni Ṣodiyan n wa ni gbogbo ọna, ko si yẹ fun ipo nitori pe ko kun oju oṣuwọn. Emi ni mo muu wọnu ẹgbẹ VGN l'ọdun 2017 n'igba ti a n ṣe atunto. Mo ni i lọkan nitori pe o maa n wa gbaaye lati lo awọn ọmọ wa ṣiṣẹ nigba to ba ni ode ariya tabi eto kan.

"Mo ni lati fi to awọn alaṣẹ wa leti nigba ti mo muu wọle, ti wọn si fun un niwe igbanisiṣẹ (appointment letter). Ko pẹ ni mo ṣakiyesi wi pe o fẹẹ maa lo ọgbọ arekereke lati de wa si meji, o n lo awọn ọmọ ẹgbẹ VGN lodi si awọn alaṣẹ n'ipinlẹ Ogun. A ṣe iwadii, a si ri aridaju, eyi lo jẹ ka fun un n'iwe ẹsun (queery). Ko fẹẹ gba iwe-ẹsun naa, ṣugbọn pẹlu ọrọ iyanju Baba Ẹlẹkunmẹfa ni Rẹmọ lo fi gba iwe-ẹsun naa, o si dahun ẹsun naa. A dariji.

"Ko pẹ lo tun bẹrẹ iwa kan naa yii, to si tun gba iwe-ẹsun. Igba to di ẹlẹẹkẹta lo salọ, ti a ko si ri i mọ lati ọdun 2017. A ko ri i mọ rara, a ko mọ ibi to gba lọ. Laipẹ yii la bẹrẹ si i ri lori ikanni ayelujara, to n gbe e sibẹ wi pe oun ti di Harmonized VGN. O ni Gomina ti ṣeleri f'oun wi pe oun ni ọga agba Harmonized VGN. Ko ṣee ṣe ki ọmọṣẹ ti ko ni ipo kankan di ọga agba. Ipo lo n wa, to si n pe awọn ọmọ ẹgbẹ wa lati purọ fun wọn.

"Fọto to gbe jade nipa ipade ti a ba oludamọran pataki fun Gomina lori ọrọ eto aabo ṣe lo jẹ lori ọrọ Amọtẹkun nikan la ṣee le lori, to ba dabi irọ, ẹ le beere lọwọ oludamọran pataki naa."

N'igba to n sọrọ lori bi ọkunrin naa ṣe n sọ pe So-Safe Corp ati VGN ti n fẹ di ayọkan, Adedoyin sọ pe "Ibi to yẹ k'awọn eeyan ti fura si ọrọ rẹ niyẹn. Ileeṣẹ kan ni VGN, ileeṣẹ mi in ni So-Safe, ti onikaluku si ni iwe ofin to gbe wọn ro.

"Mo le ṣapejuwe Ṣodiyan gẹgẹ bi Azazul to n gbiyanju lati gba ipo lọwọ ọga ẹ ni tipatipa. Angẹli agabagebe lo jẹ lati wa ipo ọla lọnakọna, ti ko si le ri i. Bi ẹ ba ranti Azazul to fẹẹ gba ipo lọwọ Ọlọrun, nigba ti ko ri ipo naa gba, Ọlọrun lee danu, bẹẹ gẹlẹ ni ọrọ rẹ ri.

"Ẹsẹ ofin la maa fi mu Ṣodiyan pẹlu ọrọ to n sọ kaakiri, awa ki i ja lai tẹle ofin. talo fun un lagbara to le maa fi sọrọ nipa VGN, ko ni aṣẹ kankan lati sọrọ nipa nnkan to n ṣẹlẹ ninu VGN."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI