AṢIRI PASITỌ TO JI ỌLỌKADA GBE TU NI ṢAGAMU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 30, 2020

AṢIRI PASITỌ TO JI ỌLỌKADA GBE TU NI ṢAGAMU


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede yii ti tẹ ogbologbo ajinigbe kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Job Jonathan, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o ji oṣiṣẹ ileeṣẹ kan to maa n pin ọja kaakiri.

Lẹyin ọjọ kẹwaa ti wọn ni Jonathan ji oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ta a f'orukọ bo laṣiri gbe gbe ni ọwọ palaba rẹ to o segi.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni Job Jonathan ni oludasilẹ ṣọọṣi kan ti wọn pe ni New Life Church of God to wa n'ilu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun.

Wọn ni ọsẹ to lọ lọhun ni Jonathan ra ọja lọwọ ileeṣẹ naa lori ayelujara, ti wọn si ran oṣiṣẹ to n ba wọn pin ọja kaakiri lọ silu Ikorodu n'ibi ti Jonathan kọ wi pe oun n gbe.

Bi ẹni naa ṣe de ilu Ikorodu ni wọn lo o pe Jonathan, ti wọn si lo o sọ pe ilu Ṣagamu ni ko ti wa a ba oun, nitori pe ibẹ loun n gbe, ki i ṣe Ikorodu. Eyi lo mu kẹni naa gbera lọ sibẹ lati gbe ọja to ti san owo rẹ fun un.

Wọn ni bo ṣe debẹ ni wọn ti gba aṣọ lọrun ọkunrin naa, ti wọn si juu sinu koto kan to wa ninu ṣọọṣi ẹ. Gbogbo igbiyanju ọkunrin yii lati bọ lọwọ Jonathan at'awọn oṣiṣẹ ẹ lo ja si pabo.

Lẹyin ojọ mẹwaa gbako ti wọn l'awọn ọga agba ileeṣẹ naa ko ri ẹni ti wọn fi ọja ran lo mu ki wọn lọ fi to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si tọpinpin ẹ de ṣọọṣi Jonathan nilu Ṣagamu, nibi ti akara wọn ti tu sepo.

Yatọ si Jonathan t'ọwọ ẹ segi, ọwọ tun tẹ awọn gendekunrin mẹta kan ti wọn ba Jonathan ṣiṣẹ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede yii, Frank Mba n'igba to n f'oju awọn eeyan naa han n'ilu Abuja sọ pe ikọ ọtẹlẹmuyẹ wọn lo ṣiṣẹ naa, ti wọn fi gbe wọn, to si fidi rẹ lelẹ wi pe gbogbo wọn ni wọn yoo foju winna ofin bi iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI