ARA TUN SAN PA MALUU MEJE L'ỌṢUN, NI OLUFỌN BA TU AṢIRI TO WA N'IDI Ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 9, 2020

ARA TUN SAN PA MALUU MEJE L'ỌṢUN, NI OLUFỌN BA TU AṢIRI TO WA N'IDI Ẹ


Iyalẹnu l'ọrọ ara to tun san pa maluu ti ko din ni meje l'abule Elepo to wa ni Ifon, ipinlẹ Ọṣun ni nnkan bi aago mẹta aarọ ọjọ Iṣẹgun to kọja yii.

Awọn maluu naa ti wọn jẹ ti ọmọ Seriki ilu Ifọn, Alaaji Abdullahi to jẹ Fulani darandaran la gbọ pe ara naa san pa.

Ojo wẹliwẹli kan la gbọ pe o rọ laarọ ọjọ naa ko to o di pe ara yii san, to si pa meje ninu awọn maluu to wa ninu ọgba.

Olufọn t'ilu Ifọn, Ọba Almaroof Magbagbeọla n'igba to n sọrọ sọ pe lara ibinu Ọlọrun si ile aye lo ṣokunfa bi ara naa ṣe pa awọn maluu yii, to si ni arun koronafairọọsi ni akọkọ iya naa.

Kabiyesi naa sọ pe oun ti ṣeto bi wọn ṣe sin oku awọn maluu naa ko to di pe wọn bẹrẹ si i ta f'awọn ti mọ nnkan to ṣẹlẹ lati jẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI