O PARI O! AJỌ CAN FI ẸSUN JIBITI KAN ALAAFIN ỌYỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 9, 2020

O PARI O! AJỌ CAN FI ẸSUN JIBITI KAN ALAAFIN ỌYỌ

Ajọ onigbagbọ lorilẹ-ede Naijiria, Christian Association of Nigeria, ẹka t'ipinlẹ Ọyọ lo ti f'ẹsun jibiti kan Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi wi pe o n ta ilẹ to jẹ ti wọn.

Wọn ni ọdun 90s ni Ọba Adeyẹmi ti ta ninu awọn ilẹ pulọọti mẹrindinlọgọrun-un to jẹ tiẹ, eyi to wa lagbegbe Ayetoro f'awọn ileeṣẹ to n ri si idasoke lori ọrọ ilẹ.

Lara ilẹ naa ni wọn sọ pe ajọ CAN ra, paapaa pẹlu ontẹ ijọba. Wọn ni awọn ilẹ yii ni Alaafin tun n ta f'awọn kan, eyi ti wọn ni ko bojumu.

Ajọ CAN sọ pe o ti pẹ t'awọn ti n gbiyanju lati ba Alaafin ṣe ipade lati mọ idi to fi n ta ilẹ naa, ṣugbọn ti wọn ni Alaafin ko fi oju silẹ fun wọn.

Gbogbo akitiyan ati igbesẹ lati ba Alaafin ṣe ipade lori ọrọ ilẹ yii ni wọn loo ja si pabo, idi ree ti wọn fi ṣe iwọde lati fẹhonu han.

Ọkan lara awọn igbimọ ajọ CAN, Rẹfurẹndi Fẹmi Afọlabi sọ pe ṣe lawọn ajagungbalẹ kọlu wọn n'igba t'awọn lọ ṣe abẹwo sori ilẹ naa, to si ni ko ṣẹyin Alaafin, idi pataki to lawọn fi ṣe iwọde ifẹhonu han.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ Aafin to sọrọ sọ pe abuku nla gba a ni lati fẹhonu han tako Alaafin pẹlu ipo rẹ lorilẹ-ede yii, paapaa n'ilẹ Yoruba, to si lo jẹ ohun iyalẹnu pe ajọ Kristẹni le wọ Baba naa nilẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI