AYE GBẸGẸ! Ẹ TUN WO OJU BABA TO FUN ỌMỌ RẸ, ỌMỌ ỌDUN MẸRINDINLOGUN LOYUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 18, 2020

AYE GBẸGẸ! Ẹ TUN WO OJU BABA TO FUN ỌMỌ RẸ, ỌMỌ ỌDUN MẸRINDINLOGUN LOYUN


Ko wa sẹni to mọ ibi ti aye n dori kọ mọ bayii lori awọn baba ti wọn n ko ibasun fun ọmọ bibi inu wọn, boya ka sọ pe aye lo n ṣe wọn ni, tabi ka sọ pe ifẹ ti wọn ni s'awọn ọmọ wọn lo fa a, ko ti i sẹni to le sọ pato.

Laipẹ yii l'aṣiri baale ile, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta kan, Eromosele Mahmud ti wọn lo o fun ọmọ rẹ loyun tun tu sita n'ilu Porth Harcourt, ipinlẹ Rivers.

Ọdun marun sẹyin, iyẹn nigba ti ọmọ naa ti wa l'ọmọ ọdun mejila la gbọ pe Eromosele, ọmọ bibi ilu Esako West, n'ipinlẹ Edo naa ti n ba ọmọ rẹ laṣepọ karakara, iyẹn ni pe o ti sọ ọ di iyawo ile rẹ.

AWIKONKO gbọ pe oyun oṣu meji gbako lo wa ninu ọmọ naa bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, to si l'oun ko le ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ rara, to si n bẹbẹ fun idariji wi pe oun tọju ọmọ naa toyun-toyun titi digba ti yoo fi bimọ, nitori pe oun ko le fọwọ si i lati yọ oyun naa.

Eromosele sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun loun ja ibale ọmọ naa, toun si ti sọ ọ di ounjẹ ọjoojumọ fun un, o ni nigba to ya, ọmọ naa lo tun maa n f'ipa mu oun lati laṣepọ.


Ọrọ ti Ermosele sọ, to n ya ọpọ eeyan lẹnu ni pe "Ogun ọdun pipẹ ti mo n ja ree, to si kọja agbara mi. Mi o ni figba kan bo ọkan ninu. To ba jẹ eyi ni yoo kọ ọmọ lọgbọn nigba ti mo ba wa lọgba ẹwọn, o tẹ mi lọrun. Ohun to n dun mọ mi ninu bayii ni pe mo ti ja ajabọ ninu wahala yii bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yii.


"Mi o le ranti igba to bẹrẹ, nitori pe o kọja oju lasan"

N'igba t'oun naa n sọrọ, ọmọ naa sọ pe n'igba toun ba n sọ pe oun ko ṣe, ṣe ni baba oun maa n lu oun, ti ko si ni san owo ileewe oun lati fiya jẹ oun.


O ni lọjọ t'awọn maa kọkọ ṣe e, ṣe ni baba oun fipa mu oun, nigba to si louin fẹẹ pariwo, ṣe lo sọ pe koun gbe ẹnu dakẹ nitori nnkan ti gbogbo eeyan n ṣe ni.


Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Nnamdi Omoni sọ pe o ti di dandan ki Eromosele f'oju ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI