LẸYIN ỌDUN MẸRINDINLOGUN, ẸGBẸ AGBABỌỌLU LEEDS UNITED PADA SI PREMIER LEAGUE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 17, 2020

LẸYIN ỌDUN MẸRINDINLOGUN, ẸGBẸ AGBABỌỌLU LEEDS UNITED PADA SI PREMIER LEAGUE

Ṣẹnkẹn bayii ninu gbogbo awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Leeds United kaakiri agbaye n dun lori bi wọn ṣe pada sori papa ti idije Premier League lẹyin ọdun mẹrindinlogun ti wọn ti lọ fẹyinti.
 
Ko si nnkan meji to jẹ ki ẹgbẹ agbabọọlu naa yege fun idije Premier League,  bi ko ṣe bi ẹgbẹ agbabọọlu West Brom ṣe kọ lati foju ẹgbẹ agbabọọlu Huddersfield gbolẹ lalẹ oni, Fraide.

Ọdun 2014 la gbọ pe wọn ti fidi rẹmi nibi idije naa, bo tilẹ jẹ oe wọn fi agidi wọ idije League One laarin ọdun 2007 si ọdun 2010, ki wọn to o tun fẹyinti fungba diẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI