Lónìí ní wọn tún kéde ikú kọmiṣanna fún eto ìlera nipinlẹ Òndó, Ọgbẹni Wahab Adegbenro tí wọn ní àìsàn koronafairọọsi, ìyẹn COVID-19 lo ṣekú pá a.
Ọkàn lára àwọn alẹnulọrọ nìdí iṣẹ ìjọba lo fi ìròyìn náà síta wí pé Ọgbẹni Wahab tí jẹ ìpè Ọlọ́run, tó sì ti padà síbi tó ti wà.
Lati bí ọsẹ mélòó kan ni Gómìnà ipinlẹ náà, Arákùnrin Rotimi Akeredolu tí wá ní igbele fún ìtọ́jú àrùn náà lẹ́yìn tí ayẹwo sọ pé ó ti kó o.
A gbọ pé látìgbà tí Adegbenro tí ni àrùn náà lo tí ń tọju ara rẹ fúnra ẹ gẹ́gẹ́ bí eleto ìlera àti oníṣègùn oyinbo, tí wọn sì ni fúnra rẹ lo ń dá oogun lo.
Aarọ òní ni wọn sọ pé ọ̀rọ̀ náà yiwọ mọ ọn lọ́wọ́, tí wọn sì sáré gbé e lọ sí ọsibitu FMC tó wà n'ilu Iwo, ipinlẹ náà fún ìtọ́jú, ṣùgbọ́n tó padà kú síbẹ̀.
No comments:
Post a Comment