BUHARI AT'AWỌN ỌRẸ RẸ̀ WỌ GAU LÓJÚ Ọ̀NÀ ÈKÓ SÌ ÌBÀDÀN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 19, 2020

BUHARI AT'AWỌN ỌRẸ RẸ̀ WỌ GAU LÓJÚ Ọ̀NÀ ÈKÓ SÌ ÌBÀDÀN


Lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí tán, ọgbà àwọn ọlọ́pàá kogberegbe, ìyẹn SARS ni àwọn afurasi adigunjale mẹ́ta tí ẹ ń wo yìí wá, níbi tí wọn tí ń ṣàlàyé ohun tó sún wọn dé ìdí iṣẹ́ idigunjale. 

Ayuba Buhari, Uzefa Idris ati Adamu Yakubu là gbọ pé wọn kò n'iṣẹ méjì ju kí wọn d'awọn èèyàn lọ́nà lopopona Èkó sì Ìbàdàn láti gba gbogbo owó àti dúkìá ọwọ wọn lọ. 

Ọjọbọ, Tọside to kọjá yìí lọ́wọ́ palaba wọn segi lágbègbè Alapako to wá lójú ọ̀nà Èkó sì Ìbàdàn nígbà tí wọn sọ pé àwọn mẹtẹẹta pẹ̀lú àwọn mi in táwọn tí na pápá bora dá mọto bọọsi Mazda elero kan dúró, tí wọn sì gba gbogbo dúkìá ọwọ wọn. 

Lára àwọn tí wọn rí nnkan tó ń ṣẹlẹ̀ là gbọ pé wọn ranṣẹ sáwọn ọlọ́pàá Owode-Ẹgba, táwọn yẹn náà sì ranṣẹ sì àwọn ọlọ́pàá kogberegbe yìí láti lọ kojú wọn. 

Lójú ẹsẹ ni wọn ti debẹ láti kọlù wọ́n. Bí wọn ṣe rí àwọn olopaa yìía gbọ wọn tí júbà ehoro, ṣùgbọ́n tí wọn lé wọn, tó sì jẹ pe mẹ́ta péré ni wọn rí mú.

Awakọ náà, Zacheaus Ọlaniyi àti ọkàn lára àwọn tó wà nínú mọto náà, Oluwakẹmi Oyegade tí wọn gba owó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹẹdẹgbẹta àti marundinlaadọta {545,000} ni wọn ṣàlàyé pé ṣe làwọn ọ̀daràn náà sáré jáde láti inú igbó sì wọn. 

Ọọdunrun-din-lẹgbẹrun-lọna-ọgọrun {99,700} náírà là gbọ pé wọn rí gbà lọ́wọ́ àwọn tọwọ tẹ yìí, tí kọmiṣanna ọlọ́pàá sì ti pàṣẹ pé kí wọ́n rí í dájú pé ọwọ tẹ àwọn yòókù lẹ́yìn ìwádìí láti lè tètè f'oju wọn ba ilé ẹjọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI