ṢANGBA FỌ! EYÍN ONÍRÒYÌN FO YỌ NÍBI TO TÍ Ń KA ÌRÒYÌN L'ORI TẸLIFIṢAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 19, 2020

ṢANGBA FỌ! EYÍN ONÍRÒYÌN FO YỌ NÍBI TO TÍ Ń KA ÌRÒYÌN L'ORI TẸLIFIṢAN


Ara meeriri, ni ọrọ obinrin akaroyin kan l'orilẹ-ede Ukraine, Marichka Padalko, ti eyin ẹnu rẹ fo yọ lasiko to n ka iroyin lori tẹlifisan.

Ṣugbọn, ko si iku ti yoo pa agba, tao ni ba poolo ori rẹ nibẹ ni Marichka fi ọrọ 'itiju' naa ṣe.

Niṣe lo rọra mu eyin akonisita bi ọmọ ọjọ mẹjọ naa dani, to si rọra n ba iṣẹ rẹ lọ.

Skip Instagram post, 1

End of Instagram post, 1

Marichka kọ sori ayelujara Instagram rẹ pe oun ro pe awọn to n wo oun lori tẹlifisan ko ni mọ nkan to ṣẹlẹ.

"Ha! ko si nkan ti oju awọn to n wo wa nile ko le ri o, a kan maa n f'oju kere akiyesi awọn onworan ni."

Marichka jẹwọ pe lootọ ni o yẹ ki oun ti ṣatunṣe eyin oun lati bi ọdun mẹwa, lẹyin ti ọmọ rẹ ṣeeṣi fi aago onirin kan gba a l'ẹnu.

O ni oun dupẹ fun atilẹyin ti oun ti ri gba lọwọ awọn to ti wo fidio naa lori ẹrọ ayelujara Youtube.

O fi kun un pe, "ninu ipokipo ti o ba ba ara rẹ, ma jẹ ki ọkan rẹ ko daru".

BBC 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI