BUHARI KANMINU LORI IKU ISA FUNTUA, O TUN FI LẸTA IBANIKẸDUN SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 21, 2020

BUHARI KANMINU LORI IKU ISA FUNTUA, O TUN FI LẸTA IBANIKẸDUN SITA

Aarẹ orilẹ-ede Naijjiria, Muhammadu Buhari ti kanminu lori iku agba ọjẹ nidi iṣẹ iroyin, Malaamu Ismaila Isa Funtua to d'oloogbe l'ọjọ Aje, Mọnde, ana.

Isa Funtua to jẹ oludasilẹ iwe-iroyin 'The Democrat', ẹni to tun jẹ alaga tẹlẹri fun ẹgbẹ awọn oludasilẹ ati alakoso iwe-iroyin lorilẹ-ede Naijiria tẹlẹ la gbọ pe aisan kan loṣeku pa a ni alẹ ana lẹni ọdun mẹrindinlọgọrin (76).

Amugbalẹgbẹ pataki fun Aarẹ lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Garba Shehu ninu atẹjade to fi sita sọ pe ibanujẹ nla n'iku Funtua jẹ fun Aarẹ nigba to gbọ iroyin naa.

Ọkan pataki lara awọn to ja fun Aarẹ Buhari lati wọle sipo naa ni Funtua, ọmọ bibi ipinlẹ Katsina naa jẹ, to si tun jẹ ọkan lara awọn alatako Buhari n pe ni kabal.

Oni ni wọn yoo sinku Funtua n'ilana musulumi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI