NITORI AIGBỌRAN SI ILANA KORONAFAIRỌỌSI, AWỌN ARAALU YOO RUGI OYIN NI KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 21, 2020

NITORI AIGBỌRAN SI ILANA KORONAFAIRỌỌSI, AWỌN ARAALU YOO RUGI OYIN NI KWARA


Ijọba yoo tun b'awọn olori ẹsin Musulumi ṣepade l'Ọjọru
Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, ẹni ti ọwọ ba tẹ wi pe o tapa si ofin ati ilana lati dẹkun itankalẹ arun koronafairọọsi n'ipinlẹ Kwara yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ gẹgẹ bi ileri ti ijọba ipinlẹ naa ṣe l'ọjọ Aje, Mọnde ana.

Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ọna t'awọn araalu n gba lati tapa si ofin ati ilana didẹkun itanakalẹ arun Covid-19 n kan oun lominu, ati pe o n ba ohun ninu jẹ pẹlu, eyi to mu ko sọ pe ọna t'awọn fẹẹ gba fi ẹsẹ ofin naa mulẹ lasiko yii yoo yatọ si ti tẹlẹ.

Akọwe Gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, ẹn to tun jẹ agbẹnusọ fun igbimọ iṣakoso eto Covid-19 n'ipinlẹ naa lo sọ ọ di mimọ f'awọn oniroyin pe bẹrẹ lati ọjọ Ẹti, Fraide ọsẹ yii, awọn araalu gbọdọ wa ninu ile wọn ni titpatipa, iyẹn bi wọn ko ba fẹẹ lo ibomu-boju tabi jinna si ara wọn.

O ni o ti pọn dandan f'awọn araalu lati maa lo aṣọ ibomu-boju lawujọ, to si lo n jẹ nnkan to n dun ijọba lọkan wi pe awọn araalu ko gbọran si aṣẹ ijọba.

Ajakaye sọ pe awọn to ba tapa si aṣẹ ati ilana lati dẹkun itankalẹ arun naa, paapaa awọn to n ṣi ṣọọbu, awakọ elero tabi aladani ni awọn agbofinro yoo mu, ti wọn yoo si f'oju ba ile-ẹjọ bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu yii gẹgẹ bi ilana didẹkun itankalẹ aisan ati arun t'ipinlẹ naa t'ọdun 2020 {Kwara State Infectious Diseases Regulations 2020).

Nibẹ naa lo tun ti jẹ ko di mimọ pe ijọba yoo b'awọn olori ẹsin musulumi ṣe ipade l'Ọjọru, Wẹside ọla fun ipalẹmọ ayẹyẹ ọdun Ileya to n bọ lọna, eyi to maa n mu k'awọn eeyan korajọ.
Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ati igbakeji rẹ, Kayọde Alabi ti lọ fun ayẹwo arun naa, eyi to sọ pe digbi ni wọn wa, to si tun fi kun un pe diẹ lara awọn oṣiṣẹ ijọba ni wọn ti ko arun naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI