ẸMIR ILU ILỌRIN, ABẸNUGỌN ILE IGBIMỌ AṢOFIN IPINLẸ KWARA SỌRỌ LORI IKU BABA GOMINA ABDULRAZAQ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 25, 2020

ẸMIR ILU ILỌRIN, ABẸNUGỌN ILE IGBIMỌ AṢOFIN IPINLẸ KWARA SỌRỌ LORI IKU BABA GOMINA ABDULRAZAQ

Ẹmir t'ilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu Gambari ti ba awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, awọn ọmọ ipinlẹ Kwara to fi mọ Gomina ipinlẹ naa, Abdulrahman Abdulrazaq kẹdun iku Alaaji A.G.F. Abdulrazaq.

Ninu lẹta ibanikẹdun ti agbẹnusọ fun Ẹmir, Abdul Azeez Arowona fi sita lonii lo ti ṣapejuwe Oloogbe AbdulRazaq gẹgẹ bi awokọṣe to pari iṣẹ sibi to dara.



Ninu ọrọ abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara ni tirẹ, Onimọ-ẹrọ, Yakubu Danladi Salihu sọ pe awokọṣe to jẹ kọmiṣanna eto iṣuna, ilera ati igbe afẹ akọkọ n'ipinlẹ naa ni Naijiria padanu lasiko ti wọn nilo rẹ.


Salihu sọ pe baba yii lo kọkọ da ile-ẹkọ alakọbẹrẹ silẹ n'ilu Ilọrin, yatọ si pe o jẹ agbẹjọro akọkọ l'Ariwa orilẹ-ede yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI