BONKẸLẸ NI WỌN FẸẸ SINKU AGF ABDULRAZAQ N'ILỌRIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 25, 2020

BONKẸLẸ NI WỌN FẸẸ SINKU AGF ABDULRAZAQ N'ILỌRIN

Gbogbo mọlẹbi Oloogbe AGF AbdulRazaq ti sọ pe awọn ko fẹ ero pupọ nibi isinku baba naa to jade laye laarọ oni, Abamẹta.

Gẹgẹ bi atẹjade ti ọkan lara awọn baba naa, to tun jẹ agbẹnusọ fun mọlẹbi, Dọkita Alimi Abdulrazaq fi sita laipẹ yii, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti sọ pe bonkẹlẹ l'awọn fẹẹ ṣe isinku baba awọn, nitori naa l'awọn ko ṣe le faaye gba ero rẹpẹtẹ.

Ninu atẹjade naa ni wọn tun ti sọ pe ki i ṣe pe o wu wọn lati ṣe oku naa bẹẹ, nitori pe oku orilẹ-ede Naijiria ni Alaaji AGF Abdulrazaq jẹ, ṣugbọn lati le tẹle ofin ati ilana jijina-diẹ-sira-ẹni lati dẹkun itankalẹ ajakalẹ arun Covid-19 lo jẹ k'awọn gbe igbesẹ naa.

Alimi sọ pe ki ẹnikẹni to ba nifẹẹ lati mọ bi nnkan ṣe n lọ nibi eto isinku naa ṣi redio rẹ si redio ipinlẹ Kwara, 99.1FM lati maa gbọ bi nnkan ṣe n lọ nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI