GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀, KASNATY FẸẸ DABIRA L'ỌJỌ ỌDÚN ILÉYÁ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 30, 2020

GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀, KASNATY FẸẸ DABIRA L'ỌJỌ ỌDÚN ILÉYÁ


Bí wọn ba n dárúkọ àwọn ìlú-mọ-ọn-ká sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tí òkìkí rẹ ń kan káàkiri àgbáyé lásìkò yìí, kò sì ẹni méjì bí kò ṣe Kọlawọle Atanda Adejojo, ẹni tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tún mọ sì Kasnaty Sugar.

Kasnaty tí gbé iṣẹ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kọjá ibi táwọn èèyàn fojú sì tẹ́lẹ̀, ó sì ti di ti gbogbo àgbáyé, ìyẹn intanaṣọnna {International} báyìí, kí í ṣe tẹnu.

Eto kan tí ọkùnrin náà bẹrẹ pẹ̀lú ère àti awada lo tí wá a di èyí táwọn èèyàn lagbaye ń gba tiẹ̀, tó sì ti mú káwọn ileeṣẹ ńlá-ńlá àti àjọ aladani máa pè é fún ibaṣepọ tó dán mọnran. 

Láàárín oṣù kẹta ọdún yìí sí àsìkò yìí, kò ti í sì àgbègbè tàbí ìgbèríko tí Kasnaty kò ti í gbé eto rẹ tí orí ayélujára, èyí tó pé ní STREET VOICES WITH KASNATY de n'ilẹ Yorùbá àti àgbègbè ẹ. 

Ohun tó tiẹ̀ wá a yà àwọn èèyàn lẹ́nu ni pé eto naa ti rán ọpọ àwọn èèyàn lọ́wọ́ káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, tó sì ti sọ àwọn tí wọn kò rí jẹ́ tẹ́lẹ̀ di ẹnì tó ń ṣàánú. 

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, wọn ní ọjọ́ ọdún Ileya tí yóò wáyé lọ́jọ́ Ẹti, Fraide ọ̀la káàkiri àgbáyé ni gbajumọ pedepede náà tún ti gbaradi láti gba ọ̀nà àrà yọ f'awọn olólùfẹ́ rẹ.

Ileya Àrà-Ọ̀tọ̀, ìyẹn Ileya Special lo pé àkọlé eto náà, níbi tí yóò ti máa lọ káàkiri láti jẹ ki awọn èèyàn mọ bí nnkan ṣe ń lọ sí í. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ti í lé fìdí ìlú tí Kasnaty ń lọ lọtẹ yìí lásìkò tá a kọ ìròyìn yìí tán, ṣùgbọ́n tí a gbọ pé gbajugbaja Aafa kan, tí wọn ń pè ní Alaaji Sulaiman Munirudeen tí wọn tún ń pè ní Baba Ọpẹ yóò máa farahàn lórí eto naa. 



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI