GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ B'AWỌN ẸLẸ́SÌN MÙSÙLÙMÍ ṢAJỌYỌ ỌDÚN ILÉYÁ, BẸ́Ẹ̀ LO TUN GBÀDÚRÀ FÚN WỌ́N - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 31, 2020

GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ B'AWỌN ẸLẸ́SÌN MÙSÙLÙMÍ ṢAJỌYỌ ỌDÚN ILÉYÁ, BẸ́Ẹ̀ LO TUN GBÀDÚRÀ FÚN WỌ́N


Bí gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí káàkiri àgbáyé ṣe ń ṣe ajọyọ ayẹyẹ ọdún Ileya tí ọlọdọọdun wọn, ìyẹn Eid-ul-Adha lónìí ọjọ́ Ẹti, Fraide, Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara náà tí fi ìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn tó ń kópa nínú ayẹyẹ náà, tó sì bá wọn yọ. 

Nínú atẹjade ibaniṣajọyọ tí akọwe ìròyìn Gómìnà, Rafiu Ajakaye gbé síta, èyí tó fi ranṣẹ sì AWIKONKO lo tí fi imọriri rẹ hàn sáwọn àgbààgbà ẹsin náà, pàápàá nipinlẹ Kwara, lórí akitiyan àti ifọwọsowọpọ wọn láti ríi pé ìdàgbàsókè de ba ìpínlẹ̀ náà. 

Bákan náà lo gbàdúrà sí Ọlọ́run láti dawọ ajakalẹ àrùn Covid-19 tó ń dá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti gbogbo àgbáyé láàmú, kò sì dáàbò bo ẹ̀dá èèyàn kúrò lọ́wọ́ irúfẹ́ ajakalẹ tó tún lè dìde. 

S'iwaju sì í lo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹmir tilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari àtàwọn ilé ìjọsìn pátápátá fún ibaṣepọ tó dán mọnran pẹ̀lú ìjọba, pàápàá àwọn ìlànà tí wọn jọ bù ọwọ lu ṣáájú àsìkò ayẹyẹ ọdún Ileya yìí. 

Gómìnà AbdulRazaq wá a rọ gbogbo àwọn aráàlú láti rí ajakalẹ àrùn yìí gẹ́gẹ́ bí ìdánwò láti ọ̀dọ̀ Adẹdaa, èyí yẹ kí gbogbo àwọn àwọn èèyàn ni igbagbọ nínú Ọlọ́run, pẹ̀lú ikora-ẹni-n-ijanu, àti ìpinnu láti gbógun ti ọ̀tá nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà tó lè dẹ́kun àrùn náà. 
 
Bẹ́ẹ̀ lo tún rọ àwọn èèyàn, pàápàá àwọn Mùsùlùmí láti lo ọjọ́ Arafat wọn, kí wọn fi gbàdúrà sí Ọlọ́run láti fi ojú àánú wo ìran ẹ̀dá.

Lákòótán, ó ní kí oníkálukú ṣe ayẹyẹ ọdún náà nínú ilé rẹ, kí wọn sì rí í pé wọn ń wá ní ikiyesara láti má je ki àrùn náà tán káàkiri. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI