GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ B'ÀWỌN ALÁṢẸ ILE-ẸKỌ ỌKỌ ÒFURUFÚ ṢE ÌPÀDÉ ÀLÀÁFÍÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 2, 2020

GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ B'ÀWỌN ALÁṢẸ ILE-ẸKỌ ỌKỌ ÒFURUFÚ ṢE ÌPÀDÉ ÀLÀÁFÍÀ


Ọjọru, Wẹside àná ni Gómìnà ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ṣe abẹwo sì olu-ileeṣẹ tó ń rí sì ọkọ òfuurufú lórílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn Nigerian Air Force. 

Abẹwo náà kò ṣẹyin ọ̀nà láti tọwọ bọ ìwé àdéhùn tuntun lórí bí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wọn méjì tí gbé kúrò n'ilu Ilọrin yóò ṣe padà, táwọn aráàlú yóò sì máa jẹ àǹfààní gidi nibẹ.

Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ náà ọmọ ogún, Military Institution àti ti ọkọ òfuurufú, ìyẹn International Aviation College {IAC} la gbọ pé wọn tí gbé lọ sí orílẹ̀-èdè South Africa lẹ́yìn àárín ohun àti ìjọba ipinlẹ náà nígbà kan dàrú. 


Ọga àwọn òṣìṣẹ́, Chief of Air Staff, Air Marshal Abubakar Sadique, to gba Gómìnà lálejò bẹbẹ fun àwọn nǹkan tó fà á tí wọn fi gbé ilé-ẹ̀kọ́ náà kúrò n'ilu Ilọrin. 

AWIKONKO gbọ pé owó idanilẹkọọ táwọn alaṣẹ kò jẹ lo dá wàhálà silẹ, èyí tó fà á tí wọn fi gbé ilé-ẹ̀kọ́ náà lọ sí South Afrika tó wà báyìí. 


Ìpàdé àlàáfíà yìí là gbọ pé ó wáyé lórí ọ̀nà tí ilé-ẹ̀kọ́ náà yóò fi padà silu Ilọrin pẹ̀lú atilẹyin ìjọba Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI