L'ọjọ Ẹti, Fraide ana ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq kẹdun iku gbajugbaja oṣere ibilẹ kan, Ibrahim Arẹmu Muhammed Nuhu, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Dan-Boy.
Gomina AbdulRazaq ṣapejuwe iku Dan-Boy gẹgẹ bi opin ere alawada atijọ, eyi ti oloogbe naa jẹ ko to o ku.
Yatọ si ere awada ibilẹ ti Dan-Boy maa n ṣe, o tun gbona nidi ere idaraya, ti pupọ awọn eeyan si maa n fẹ wo o lọpọ igba.
Ohun ti ẹni akọkọ to maa n gbe ere ibilẹ ati ere idaraya rẹ kaakiri awọn ode, paapaa ode ayẹyẹ n'ilu Ilọrin. Nibi to gbajumọ de, ode ariya ko ti i pe lai jẹ pe Dan-Boy yọju sibẹ lati dawọn eeyan laraya.
No comments:
Post a Comment