GOMINA IPINLẸ KWARA PADANU BABA RẸ LẸNI ỌDUN MẸTALELAADỌRUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 25, 2020

GOMINA IPINLẸ KWARA PADANU BABA RẸ LẸNI ỌDUN MẸTALELAADỌRUN



Pẹlu ibanujẹ ọkan ni ijọba ipinlẹ Kwara fi kede iku Baba to bi Gomina AbulRahman AbdulRazaq, Alaaji AbdulGaniyu Fọlọrunṣhọ Abdul-Razaq SAN (OFR) to d'oloogbe laarọ oni, ọjọ Abamẹta.

Nnkan bi aago meji oru oni la gbọ pe Alaaji Fọlọrunṣọ AbdulRazaq dagbere f'aye n'ilu Abuja, gẹgẹ bi atẹjade ti Dọkita Alimi AbdulRazaq fi sita lati fi kede iku ẹ.

Ẹni ọdun mẹtalelaadọrun ni wọn pe Oloogbe Abdulrazaq, to jẹ agbẹjọro akọkọ ni Ariwa orilẹ-ede Naijiria. Baba naa ni Mutawali t'ilu Ilọrin ati Tafida ti Zazzau (Zaria).

Yatọ si eyi, Baba yii ti ṣiṣẹ takuntakun fun orilẹ-ede Naijiria nígba aye rẹ, to si tun jẹ aṣoju Naijiria silẹ Ivory-Coast.

Oloogbe fi iyawo, ẹni aadọrun ọdun, Hajia Raliat Abdulrazaq at'awọn ọmọ, eyi ti Gomina Abdulrahman Abdulrazaq jẹ ọkan lara wọn silẹ s'aye lọ.


Dọkita Alimi fi ye wa pe wọn yoo kede isinku Baba naa laipẹ yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI