Shaibu lo sọrọ yii nibi ipolongo idibo gomina ipinlẹ naa to n bọ lọna, eyi ti wọn ṣe loju ọna Akpakpava, ilu Benin si Ekpoma ati jattu, ijọba ibilẹ Etsako.
O ni gbogbo Ọṣhiọmhọlẹ ṣe n mu oludije sipo gomina ipinlẹ naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Osagie Ize-Iyamu bẹbẹ kaakiri lati le ri ojurere awọn eeyan ni ko lẹsẹ nilẹ, nitori pe alagabagebe ni.
Nibẹ lo tun ti sọ pe eto idibo naa ko ni i da lori bi awọn eeyan naa ṣe lọ n farahan kaakiri, bi ko ṣe pe iṣẹ ti gbogbo wọn ti ṣe silẹ ni yoo gbe wọn lẹyin lati jẹ kẹni t'awọn eeyan ba mọ si eeyan gidi jawe olubori.
Bakan naa lo sọ pe idibo yii yoo f'awọn ara ipinlẹ Ẹdo lanfaani lati pinuu ọjọ-ọla awọn ọmọ wọn, ti ki i si i ṣe asiko ti wọn n fẹ wo ere ti awọn baba-isalẹ alailaanu fẹẹ jẹ nipa iwa imọ-tara-ẹni-nikan ti wọn n ba kaakiri.
O wa ni ko ni i ṣe pẹlu iye igba ti wọn yoo maa dunkooko mọ wọn, to le da awọn duro lati ma gbe ipolongo kaakiri, ti yoo si jẹ k'awọn eeyan dibo yan wọn sipo
No comments:
Post a Comment