ÌDÌBÒ ÒNDÓ! PRIMATE AYỌDELE SỌ ÀSỌTẸ́LẸ̀ ẸNÌ TI YÓÒ JÁWÉ OLÚBORÍ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 30, 2020

ÌDÌBÒ ÒNDÓ! PRIMATE AYỌDELE SỌ ÀSỌTẸ́LẸ̀ ẸNÌ TI YÓÒ JÁWÉ OLÚBORÍ


Ija ajaku-akata to wa n'ipinlẹ naa bayii lo wa laaarin Gomina Rotimi Akeredolu ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ati oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP , iyẹn Ọgbẹni Eyitayọ Jẹgẹdẹ.

Wolii Ayọdele sọ pe ko si ẹni meji ti yoo jawe olubori ninu idibo naa bi ko ṣe pe Gomina Akeredolu ni yoo pada s'ipo rẹ lẹẹkeji, nitori pe oun l'awọn araalu yoo dibo yan, gẹgẹ bo ṣe sọ pe Ọlọrun fi han oun.

Gbajugbaja Wolii naa sọ pe ko si nnkan meji ti yoo jẹ ki oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, iyẹn Jẹgẹdẹ padanu ipo naa bi ko ṣe pe o ti ṣi ẹsẹ gbe, ko si le yege ninu idibo naa.

Ninu asọtẹlẹ ti baba naa gbe jade l'ọjọ Wẹside ana lo ti sọ pe ọna ti Jẹgẹdẹ gba ko le jẹ ko ri ojurere awọn araalu ti yoo dibo fun un, fun idi eyi, o ni ko s'ibi to n lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI