IṢẸ́NLỌ! KỌMIṢANNA ṢABẸWỌ SI ASA DAM - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 21, 2020

IṢẸ́NLỌ! KỌMIṢANNA ṢABẸWỌ SI ASA DAM


Lati tẹsiwaju atunṣe ati mimu idagbasoke b'awọn agbegbe, Kọmiṣanna f'eto iṣẹ idagbasoke, Onimọ-ẹrọ Rotimi Iliasu tun ṣe abẹwo si Asa Dam, nibi ti awọn agbaṣẹṣe ti bẹrẹ iṣẹ l'Ọjọ Mọnde ana.

Ninu awọn ileri Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo ti sọ pe awọn ko ni i ya iṣẹ tabi ẹka kankan sọtọ n'ipinlẹ naa, nitori pe gbogbo ohun to ba yẹ láwọn yoo ṣe lai fi ti ọrọ oṣelu ṣe.

Lara awọn ẹka ileeṣẹ ti iṣẹ akanṣe ti n lọ ni ẹka eto ilera, eto ẹkọ, opopona, ina mọnamọna at'awọn mi in.

Awọn eyi si ti n mu idagbasoke alailẹgbẹ ba awọn oniṣẹ-ọwọ, oniṣowo, ileeṣẹ nla ati kereje, to fi mọ awọn ọlọja igbalode ati t'ibilẹ, bẹẹ l'awọn ọdọ naa n ri iṣẹ ṣe lasiko.


#Isenlo

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI