KORONAFAIRỌỌSI! IPINLẸ KWARA GBA IWE-ẸRI NCDC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 13, 2020

KORONAFAIRỌỌSI! IPINLẸ KWARA GBA IWE-ẸRI NCDC

Ọna irọrun ni itọju awọn to lugbadi arun Covid-19 tun gba yọ n'ipinlẹ Kwara pẹlu bi ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ati aisan lorilẹ-ede Naijiria, NCDC ṣe gbe irwe-ẹri moyege lẹ ipinlẹ naa lọwọ wi pe wọn kun oju oṣuwọn lati maa tọju awọn eeyan lori arun aṣekupani koronafairọọsi.

Dọkita Fẹmi Ọladiji to jẹ oludamọran lori eto ilera fun arun Covid-19 lo fi ọrọ naa sita wi pe ajọ naa ti bu ọwọ lu ibodu ayẹwo, iyẹn, automated GeneXpert laboratory fun arun naa, eyi to wa ni Alagbado, ilu Ilọrin, to si ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI