O MA ṢE O! ÌJỌBA KWARA ṢÀLÀYÉ BI ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI ṢE PA OLÓRÍ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ GÓMÌNÀ LẸ́YÌN ỌDÚN KAN ATI OṢÙ KAN TÓ GBA IPO NÁÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 8, 2020

O MA ṢE O! ÌJỌBA KWARA ṢÀLÀYÉ BI ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI ṢE PA OLÓRÍ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ GÓMÌNÀ LẸ́YÌN ỌDÚN KAN ATI OṢÙ KAN TÓ GBA IPO NÁÀ


Pẹ̀lú ibanujẹ ọkàn ni ìjọba ipinlẹ Kwara fi kéde ikú olórí àwọn òṣìṣẹ́ Gómìnà ipinlẹ náà, Aminu Adisa Logun, ẹni tí wọn ní àrùn koronafairọọsi ṣekú pá. 

Ohun tí a gbọ ni pé ọsẹ to kọjá làwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera ṣe àyẹ̀wò koronafairọọsi, ìyẹn COVID-19 fún Logun láti mọ bóyá àrùn náà wá lára rẹ tàbí kó sì í. 

Wọn ní Logun tí ń rí àwọn àpẹẹrẹ àrùn yìí lára rẹ, èyí tó mú kó kan sáwọn eleto ìlera fún àyẹ̀wò lọsẹ tó kọjá, tí wọn sì ṣeé fún un. 

Wọn ní kí esi àyẹ̀wò náà tó o jáde ní bàbà náà tí yà ara rẹ sọtọ, tó sì ń tọju ara rẹ pẹlu iranlọwọ àwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera rẹ. 

Aminu Adisa Logun là gbọ pé ọkàn rẹ ko balẹ̀ rárá látìgbà tí wọn tí ṣe àyẹ̀wò náà fún un, nítorí tí wọn loo tí ń fura pé ó ṣeé ṣe kí wọn padà sọ pé òun ti ko àrùn kogboogun náà. 

Ọsan àná, Tuside là gbọ pé wọn mú esi àyẹ̀wò náà lọ fún un nílé wi pe àrùn náà tí wá lára rẹ, tó sì di dandan kí wọn gbé e lọ sí ọsibitu ayasọtọ fáwọn tó ní àrùn yìí láti lè túbọ̀ gba itọju gidi. 

Wọn ní bo ṣe gbọ esi náà ni ẹru bá a, ó ti ifunpa rẹ sì fà sókè lójú ẹsẹ̀. Ère ni wọn làwọn tó wà nibẹ kọ́kọ́ pé e, a fìgbà tí ọ̀rọ̀ náà yiwọ pátápátá.

Ki olójú tó o ṣẹ ẹ, Logun tí gba ekuru jẹ́ lọ́wọ́ ẹbora. 

Ní báyìí, Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí wá a kéde ọjọ́ méje gbáko láti fi kẹdun ikú Baba náà, nítorí tí wọn sọ pé pẹ̀lú inú kan ni bàbá náà fi sìn ipinlẹ Kwara, pàápàá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. 

Ohun tó ń yà pupọ àwọn èèyàn lẹ́nu ni pé àná tí í ṣe ọjọ́ keje oṣù keje lo pé ọdún kan àti oṣù kan gbáko tí Logun gba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olori àwọn òṣìṣẹ́ Gómìnà ipinlẹ náà. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI