TRUMP LE ÀJỌ WHO KÚRÒ L'AMẸRIKA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 8, 2020

TRUMP LE ÀJỌ WHO KÚRÒ L'AMẸRIKA


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Donal Trump tí pàṣẹ pé ilẹ̀ òun kò tún ní nǹkan ṣe papọ mọ pẹ̀lú ileeṣẹ eleto ìlera àgbáyé, ìyẹn World Health Organization {WHO} bí yóò bá fi di ọdún tó ń bọ̀, ìyẹn 2021.

Ọjọ́ Aje, Mọnde tó kọjá yìí ni Ààrẹ Trump kọ̀wé ranṣẹ sì ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin wọn láti fi tó wọn létí, láti lè bù ọwọ luu. 

Kò sí nnkan méjì tó mú kí Trump gbé igbesẹ yìí bí kò ṣe báwọn tó ti kú lórí ajakalẹ àrùn koronafairọọsi ṣe tí pá àwọn tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà aadọjọ {130,000},tawon èèyàn sì tún ń pàdánù ẹmi wọn lojoojumọ. 

Ìwé náà tí akọwe àgbà ilẹ̀ Amẹ́ríkà tẹwọ lo sọ pé kí àjọ WHO lọ máa palẹmọ ẹrú wọn kò too tó ọjọ́ kẹfà oṣù kejila ọdún 2021 tí wọn yóò fi ilẹ̀ náà silẹ pátápátá. 

Ọkàn lára àwọn Sẹnetọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Bob Mendez to loun náà tí gbọ nípa igbesẹ yìí bù ẹnu atẹ luu, tó sì ni kò yẹ kó jẹ́ irú àsìkò ajakalẹ àrùn yìí ni nnkan bẹẹ máa wáyé. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI