OPẸ́ O! ÌYÀWÓ AGBA-ỌRỌ, GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ BÍMỌ LẸ́YÌN ỌDÚN MẸ́TÀLÁ ÌGBÉYÀWÓ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 8, 2020

OPẸ́ O! ÌYÀWÓ AGBA-ỌRỌ, GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ BÍMỌ LẸ́YÌN ỌDÚN MẸ́TÀLÁ ÌGBÉYÀWÓ


Ko si orin méjì táwọn olólùfẹ́ gbajugbaja sọrọsọrọ orí redio nnì, Oluwaṣinaayọmi Amọdu ń bá a kọ lásìkò yìí, tó yàtọ̀ sí orin ọpẹ, lórí bí ìyàwó ẹ tuntun ṣe bímọ tuntun.

Amọdu, ẹni tí ọpọ àwọn èèyàn mọ sì Àgbá-Ọ̀rọ̀ là gbọ́ pé ọdún kẹtàlá rèé t'oun àti ìyàwó ẹ tuntun náà tí ṣe ìgbéyàwó, to sì jẹ pe látìgbà náà ni wọn ti ń woju Ọlọ́run fún ọmọ. 

A gbó pé ọjọ́ Ẹti, Fraide ọ̀sẹ̀ tó kọjá ní ìyàwó ọkùnrin náà bímọ obìnrin sì ọsibitu kan tó wà n'ilu Abẹ́òkúta, ipinlẹ Ogun, níbi tí wọn fi ṣe ibùgbé. 

Kò fẹẹ sì rédíò kan nílẹ̀ Yorùbá ti Àgbá-Ọ̀rọ̀ kò tíì ṣètò, tó fi mọ ileeṣẹ amohunmaworan, ìyẹn tẹlifiṣan, pàápàá nipinlẹ Ogun.


Eto kan tí ọkùnrin náà máa ń ṣe lórí rédíò, èyí tó fi ń rán àwọn akanda èèyàn lọ́wọ́ làwọn kan ń sọ pé Ọlọ́run wo láti fi tètè dáa lóhùn. 

Gbogbo àwọn sọrọsọrọ ẹgbẹ́ ẹ là gbọ́ pé wọn tí ń bá ọkùnrin náà ṣajọyọ lórí oriire ńlá tó wọlé tọ ọ náà, tí wọn sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dá ọmọ náà sì. 

Ọjọ́ Ẹti, Fraide to m bọ yìí là gbọ́ pé wọn yóò ṣe ikojade ọmọ náà n'ilu Abẹ́òkúta, níbi tí wẹjẹ-wẹmu yóò ti wáyé. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI