WÀHÁLÀ ŃLÁ DE B'AWỌN Ọ̀DARÀN NI KWARA, Ọ̀NÀ LÁTI FI ÌLÚ SÍLẸ̀ NI WỌN N WA BÁYÌÍ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 10, 2020

WÀHÁLÀ ŃLÁ DE B'AWỌN Ọ̀DARÀN NI KWARA, Ọ̀NÀ LÁTI FI ÌLÚ SÍLẸ̀ NI WỌN N WA BÁYÌÍ


Gbogbo àwọn ọ̀daràn àtàwọn tí wọn ń gbèrò láti daran nipinlẹ Kwara ni wọn ti bẹ̀rẹ̀ si í palẹ ẹrù wọn mọ báyìí, kí wọn lé sá kúrò nílùú nítorí bí Gómìnà ipinlẹ náà, AbdulRahman AbdulRazaq ṣe sọ pé àwọn kò lè jọ gbé inú ìlú kan náà. 

Gómìnà AbdulRazaq ló bínú sọ̀rọ̀ lànà, Tọside wí pé ọ̀daràn tí ọwọ palaba rẹ bá segi yóò ru igi oyin, tí yóò sì tún kiri ekuru lórí ọganjọ. 

Ó ní erongba òun ni kí àlàáfíà àti igbe ayé ìrọ̀rùn tó péye wá fún àwọn aráàlú, nítorí pé ààbò ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn òun ló jẹ́ òun lógún, t'oun sì gbọ́dọ̀ rí í pé wọn jẹ ìgbádùn eto òṣèlú awaarawa. 

AbdulRazaq ni òun kò ní í gba ẹnikẹ́ni tàbí ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ láàyè láti fìyà jẹ aráàlú, t'oun sì fẹẹ kí ìwà ọ̀daràn di ohun ìgbàgbé pátápátá. 

Èyí kò ṣẹyin bí Gómìnà AbdulRazaq ṣe kó àwọn ẹṣọ ààbò lọ sijọba ìbílẹ̀ Baruten láti gbógun ti àwọn afurasi ọ̀daràn tí wọ́n wá láti tẹ̀dó síbẹ̀. 

Nibẹ sì ni wọn ti gba àwọn èèyàn lamọran wí pé káwọn náà rí i pé wọn ń ṣíṣẹ ojulalakanfinṣọri. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI