MESSI ATI KOEMEN ṢE IPADE IKỌKỌ LORI ỌJỌ IWAJU BARCELONA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 21, 2020

MESSI ATI KOEMEN ṢE IPADE IKỌKỌ LORI ỌJỌ IWAJU BARCELONA

Lẹyin ti gbajugbaja agbabọọlu agbaye ni, ẹni t'awọn eeyan n'igbagbọ pe oun lo darajulọ laarin awọn akẹgbẹ rẹ, iyẹn Lionel Messi kede sita pe oun ti ṣetan lati fi ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona silẹ lẹyin ti wọn gbalejo ọran, iyẹn Bayern Munich, ti wọn si padanu gidi pẹlu aami ayọ mẹjọ si meji.
 
Nibi ipade ti Messi ba akọnimọọgba tuntun ti Barcelona ṣẹṣẹ gba, iyẹn Ronald Koemen lo ti sọ pe oun ko ri idi pataki kankan t'oun yoo tun fi duro ninu ẹgbẹ agbabọọlu naa lẹyin itiju nla t'awọn koju.
 
Messi loun ti riran pe oun ti n sunmọ lati kuro ni Blaugrana ju k'oun duro ni Camp Nou lọ. O loun ko riran naa daadaa bi ọjọ iwaju Barcelona yooo ṣe ri, nigba to n sọrọ naa.
 
Nibẹ ni Koeman ti sọ erongba rẹ fun Messi pe yoo wu oun lati duro, nitori pe ko tun si iru eeyan bi i Messi mọ lagbaye, toun si fẹ lati ba a ṣiṣẹ papọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI