ADAJỌ NI KI WỌN JU BABA ARUGBO L'OKUTA PA NITORI ỌMỌ ỌDUN MEJILA TO FIPA BA LAṢEPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 13, 2020

ADAJỌ NI KI WỌN JU BABA ARUGBO L'OKUTA PA NITORI ỌMỌ ỌDUN MEJILA TO FIPA BA LAṢEPỌ

Ile-ẹjọ Shariah kan n'ipinlẹ Kano ti da ẹjọ iku fun baba arugbo ẹni ọgọta ọdun kan, to si ni ṣe ni ki wọn juu l'okuta titi ti yoo fi f'aye silẹ.

Mati Abdu ni wọn pe orukọ Baba naa ti wọn loo f'ipa ba ọmọ kekere, ọmọ ọdun mejila laṣepọ. Ọdun to kọja níṣẹlẹ naa waye labule Farsa to wa n'ijọba ibilẹ Tsanyawa, ipinlẹ naa ti Baba naa ti wa.

N'igba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Ibrahim Sarki Yola sọ pe ẹṣẹ ti mati hu naa ko ni idariji, nitori pe iyawo wa ninu ile ẹ lasiko to lọ f'ipa ba ọmọ ọdun mejila naa laṣepọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI