GỌNGỌ FẸẸ SỌ N'IPINLẸ KWARA LORI AWỌN DUKIA IJỌBA TI WỌN TA LAAARIN ỌDUN 1999 SI ỌDUN 2019 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 13, 2020

GỌNGỌ FẸẸ SỌ N'IPINLẸ KWARA LORI AWỌN DUKIA IJỌBA TI WỌN TA LAAARIN ỌDUN 1999 SI ỌDUN 2019Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ti fi ye wa pe awọn ti wọn ra dukia ijọba ipinlẹ Kwara lọna ti ko ba ofin mu laaarin ọdun 1999 si ọdun 2019 to kọja yii ni wọn ti n wa ọna abayọ, ko da, t'awọn ti wọn ta awọn dukia naa ti n wa ọna ti wọn yoo gba bẹbẹ, ki wọn ma ba a ṣẹwọn ojiji.
 
L'ọjọ Iṣẹgun, Tuside ijẹta ni Gomina AbuldRahman AbdulRazaq gbe igbimọ nla kan dide lati ṣe iwadii kiku lori bi wọn a awọn dukia to jẹ ti ijọba laaarin ogun ọdun.
 
Yatọ si eyi, igbimọ naa yoo tun ṣe iwadii lori owo kan ti wọn pe ni ọọdunrun miliọnu (300m) naira, eyi ti wọn sọ pe o jade lati inu apo awọn ijọba ibilẹ bọ sinu apo ijọba ipinlẹ naa, iyẹn ninu owo to n wa lati ọdọ ijọba apapọ orilẹ-ede yii.
 
Oṣu mẹta gbako la gbọ pe igbimọ yii yoo fi ṣe iwadii lati mọ awọn dukia ijọba ti gba ọna ayederu ta f'awọn kan, eyi ti wọn ni ijọba ti ṣetan lai gba pada. Bẹẹ ni wọn yoo lo ọsẹ meji pere lati fi ṣe iwadii lori ọọdunrun miliọnu naira naa, eyi ti wọn tun sọ pe ileeṣẹ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, iyẹn EFCC naa ti bẹrẹ iwadii wọn.
 
Igbimọ naa ti Adajọ-fẹyinti Ọlabanji Oriloniṣhe jẹ alaga ẹ ni Gomina AbdulRazaq sọ fun pe wọn gbọdọ ṣe iwadii naa ni kikun lai yọ eyikeyi sẹyin tabi fi ẹlẹyamẹya ṣe.
 
Gomina AbdulRazaq nibi to ti n fi igbimọ naa lelẹ sọ pe eyi yoo jẹ ki awọn to wa nipo oṣelu ati adari lasiko mọ pe wọn ko gbọdọ ṣe iru aṣiṣe kan naa, ki wọn si mọ pataki bi wọn ṣe n daabo bo dukia ijọba.
 
O ni ko bojumu ki wọn ta nnkan ti wọn fi owo araalu ra lọna ti ko ba ofin mu.

Adajọ-fẹyinti Mathew Adewara, alaga; Halimah Bello (Aṣoju DSS); DSP Adekunle Iwalaiye (Aṣoju ọlọpaa); Titilayo Adedeji; Mohammed Baba Ibrahim; Bello Aisha Mohammed; Asmau Apalando; ati Arabinrin Sabitiyu Grillo ni igbimọ ti yoo ṣe iwadii lori owo ijọba ibilẹ.
 
Adajọ-fẹyin Orilonishe; Job Kolawole Buremoh; Isiaka AbdulKarem; Safiya Usman; Salihu Yaru; ati Mohammed Baba Orire ni yoo ṣe iwadii lori dukia ijọba ti wọn ta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI