AMAECHI TU AṢIRI BILIỌNU MẸTA DỌLA TI NAIJIRIA TUN FẸẸ YA LỌWỌ CHINA SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 5, 2020

AMAECHI TU AṢIRI BILIỌNU MẸTA DỌLA TI NAIJIRIA TUN FẸẸ YA LỌWỌ CHINA SITA

Minisita f'ọrọ igbokegbode ọkọ lorilẹ-ede Naijiria, Chibuike rotimi Amaechi ti sọ pe Naijiria nilo lati ya owo mi in ti ko din ni biliọnu mẹta dọla lọwọ orilẹ-ede China.

O si ni ki ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede yii ma pinu lati ṣe iwadii owo naa, nitori pe iṣẹ ilu l'awọn fẹẹ fi ṣe.

Ana ti i ṣe Tuside ni Amaechi sọrọ naa lori eto oṣelu kan to maa n waye lori tẹlifiṣan Channels, eyi ti wọn pe ni Politics Today, to si n sọ pe oun ti sọ f'awọn aṣofin lati ma ṣe tọpinpin owo naa lati le jẹ k'awọn tete ri i gba lọwọ China.

O ni oju ọna ọkọ reluwe l'awọn fẹẹ fi owo naa ṣe, eyi ti yoo lọ laaarin ipinlẹ Port Harcourt si Maiduguri.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe  “Idi ti mo fi sọ bẹẹ i pe, a ti kọ lẹta lati ya biliọnu marun le diẹ ($5.3b) tẹlẹ lati fi ṣe oju ọna reluwe to lọ lati Ibadan si Kano.

“A tun fẹẹ kọ lẹta lati ya biliọnu mẹta dọla ($3b) mi in lati fi ṣe oju ọna reluwe to lọ lati Port Harcourt si Maiduguri.

“Ẹ ma gbagbe pe ile igbimọ aṣofin lo bu ọwọ lu owo ta a kọkọ ya naa. Ko ba ofin mu lati ya owo lai ni aṣẹ ati ontẹ ile igbimọ aṣofin ninu.

“To ba jẹ pe emi ni mo fẹ ya eeyan lowo, O maa ṣe mi ni kayeefi. Ti awọn to ba fẹẹ ya owo naa ba n ṣe aniyan, wọn a sọ pe rara, awọn ko ni i bu owo lu owo ti a fẹẹ ya.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI