AWỌN ARAALU ṢI N SỌRỌ LORI AṢO IBOMU ATI IFỌWỌ TI IPINLẸ KWARA PIN FUN GBOGBO ILE-ẸKỌ GIRAMA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 19, 2020

AWỌN ARAALU ṢI N SỌRỌ LORI AṢO IBOMU ATI IFỌWỌ TI IPINLẸ KWARA PIN FUN GBOGBO ILE-ẸKỌ GIRAMA


Bi idanwo aṣekagba kuro nile-ẹkọ girama, iyẹn t'awọn akẹkọọ ṣe bẹrẹ ni pẹrẹu, Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti pin aṣo ibomu ati ọṣẹ ifọwọ fun gbogbo awọn ile-ẹkọ girama kaakiri ipinlẹ naa lojuna lati dẹkun itankalẹ ajakalẹ arun Covid-19.

Ọjọ Aje Mọnde to kọja yii ni eto naa waye, n'ibi ti Gomina ti pin ifọwọ ti ko din ni ẹgbẹrun mejilelaadọta fun alakoso fun eto ẹkọ n'ipinlẹ naa lati pin in s'awọn il-ẹkọ kaakiri s'awọn ile-ẹkọ girama ti idanwo iwe kẹwaa yoo ti waye.
Yatọ si awọn akẹkọọ SS3 ti wọn n ṣe idanwo aṣekagba wọn lọwọ ti wọn yoo jẹ ninu anfaani naa, bẹẹ l'awọn akẹkọọ JSS3 naa yoo jẹ anfaani rẹ, nitori pe awọn naa n ṣe idanwo aṣekagba wọn lọwọ.

Akọwe ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Saba Mamman Jibril to ṣagbatẹru eto naa lasiko to n sọrọ gba awọn adari (Principals) kaakiri ile-ẹkọ lamọran wi pe ki wọn rii daju pe wọn n lo lọna to yẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI