NITORI ỌBASẸKI NI MO ṢE B'AWỌN BABA ISALẸ JA L'ẸDO, ALAIMOORE NLA NI - ỌṢIỌMỌLẸ PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 19, 2020

NITORI ỌBASẸKI NI MO ṢE B'AWỌN BABA ISALẸ JA L'ẸDO, ALAIMOORE NLA NI - ỌṢIỌMỌLẸ PARIWO SITA

Alaga ana fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Kọmureedi Adams Ọṣiọmọlẹ tun ti ṣapejuwe Gomina ipinlẹ Ẹdo, gODWIN Ọbasẹki gẹgẹ bi alaimoore, nitori pe tori tiẹ l'oun ṣe kọju ija sáwọn Baba isalẹ n'ipinlẹ naa lati le jẹ ko di gomina.

Ọjọ Aje, Mọnde ijẹta ni Ọṣiọmọlẹ sọrọ yii lasiko to n b'awọn akọroyin Aso-Rock sọrọ lẹyin to ṣe ipade tan pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari nilu Abuja.

Nibẹ lo ti sọ pe pẹlu b'oun ṣe gbajumọ to, gbogbo awọn eeyan lo n bọwọ f'oun gẹgẹ bi eeyan gidi, to si ni anfaani t'oun lo jẹ káwọn eeyan dibo fun Ọbasẹki.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ko si abule ti mo de t'awọn eeyan ko mọ mi. Anfaani naa ni mo lo ti mo fi gba iyi mọ awọn baba isalẹ n'ipinlẹ Ẹdo lọwọ lẹẹmeji ọtọọtọ, ti mo si tun lo anfaani naa lati gbe Ọbasẹki de ipo to wa lonii.

Ṣaaju asiko yii ni Gomina Ọbasẹki ti sọ pe ko si owo kankan lọwọ Ọṣiọmọlẹ lasiko to jade du ipo naa l'ọdun 2007.

Bẹ o ba gbagbe, alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹ-ede Naijiria ni Ọṣiọmọlẹ tẹlẹ ko to jade du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Congress, to si padanu s'ọwọ alatako rẹ nigba naa toun jade du ipo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, iyẹn Oserheimen Osunbor.

Ọṣiọmọlẹ tako esi idibo naa, to si jawe olubori lẹyin ọdun kan ti wọn bẹrẹ ẹjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI