GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ FI LẸ́TÀ AYỌ̀ RANṢẸ SÍ OLUDASILẸ BUA, LORI AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ ỌGỌ́TA ỌDÚN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 4, 2020

GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ FI LẸ́TÀ AYỌ̀ RANṢẸ SÍ OLUDASILẸ BUA, LORI AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ ỌGỌ́TA ỌDÚN


Bí gbogbo àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé ṣe ń bá Olóyè Abdul Samad Rabiu ṣajọyọ lórí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún rẹ, Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq náà tún fi lẹ́tà ayọ̀ ranṣẹ.

Nínú atẹjade tí akọwe ìròyìn Gómìnà, Rafiu Ajakaye fi síta lónìí lo tí ṣàpèjúwe Abdul Samad Rabiu gẹ́gẹ́ bí oníṣòwò Nàìjíríà tó dá yàtọ̀ láwùjọ nípa mímú ìdàgbàsókè báwọn àgbègbè, pàápàá nipinlẹ náà. 

Gómìnà AbdulRazaq nígbà tó ń fi ọkàn akíkanjú gbajúmọ̀ oníṣòwò náà balẹ̀ lórí àyíká gidi fún iṣowo, ní ipa tí ọkùnrin náà ń kó nípinlẹ náà kò ṣeé fọwọ́ rọ́ tí sẹ́yìn.


Bẹ́ẹ̀ lo sọ pé lára àwọn nǹkan tí kò lè jẹ ki ìpínlẹ̀ náà gbàgbé Samad Rabiu ni bo ṣe jẹ́ pé òun nìkan ni aladani tí yóò ṣe iranlọwọ tó pọ̀jù fún ìpínlẹ̀ náà lórí ọ̀nà láti dẹkùn itankalẹ àrùn Covid-19. 

Ó wà gbàdúrà ẹ̀mí gígùn àti àlàáfíà fún ọkùnrin náà nínú ìlera pípé àti igbega tí kò wọ́pọ̀. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI