NǸKAN DE! IGBAKEJI GÓMÌNÀ IPINLẸ KWARA ATI ÌYÀWÓ Ẹ LUGBADI ARUN KORONAFAIRỌỌSI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 4, 2020

NǸKAN DE! IGBAKEJI GÓMÌNÀ IPINLẸ KWARA ATI ÌYÀWÓ Ẹ LUGBADI ARUN KORONAFAIRỌỌSI


Àdúrà làwọn olólùfẹ́ igbá-kejì gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, Ọgbẹni Kayọde Alabi àti ìyàwó ẹ gba fún àwọn méjèèjì lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí tán lórí bí wọn ṣe lugbadi ajakalẹ àrùn Koronafairọọsi. 

Ọjọ́ Ajé, Mọnde àná làwọn méjèèjì gba ibùdó ayẹwo lọ nígbà tí wón sọ pé wọn ń kofiri àrùn náà lára wọn, tí wọn sì ṣe ayẹwo.

Ìyàlẹ́nu lo jẹ́ pé nígbà tí esi ayẹwo náà yóò fi jáde síta, ó ṣeni láàánú wí pé wọn tí lugbadi àrùn náà, èyí tó mú káwọn òṣìṣẹ́ wọn wá nínú ibẹrubojo. 

Lásìkò tá a kọ ìròyìn yìí tán, ibi tí wọn tí ń gba ìtọ́jú ni wọn wá, ìjọba ìpínlẹ̀ náà ṣì ń gbàdúrà àlàáfíà pípé fún wọn. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI