IDAAMU NLA TUN BẸ SILẸ LORI IDIBO IMO, WOLII AYỌDELE SỌ ASỌTẸLẸ IJAYA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 19, 2020

IDAAMU NLA TUN BẸ SILẸ LORI IDIBO IMO, WOLII AYỌDELE SỌ ASỌTẸLẸ IJAYA

Inu ibẹrubojo ni Gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma at'awọn ololufẹ rẹ wa bayii lori asọtẹlẹ ibanilẹru ti alaṣẹ ati adari ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Primate Elijah Ayọdele sọ l'ọjọ Iṣẹgun, Tuside ana.

Wolii Elijah Ayọdele sọ pe o ṣee ṣe ki ile ẹjọ agba lorilẹ-ede yii tun ṣe agbeyẹwo idajọ rẹ, eyi to sọ Hope Uzodinma di Gomina ipinlẹ naa.
 

Gbajugbaja Wolii agbaye alasọtẹlẹ imuṣẹ naa sọ pe oun ko le sọ pato bi idajọ naa yoo ṣe waye, ṣugbọn to ni afi ki Gomina Uzodinma tete tara ṣaṣa lati gbe igbesẹ ki ohun ti ko lero ma ba a ṣẹlẹ si i lojiji.

Ninu atẹjade to fi sọ asọtẹlẹ naa, eyi to fi ranṣẹ s'awọn oniroyin lo ti sọ pe "Ninu eyi to da bi asọtẹlẹ ibanilẹru t'ọdun yii, ni mo ṣe n pe akiyesi Gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma lati mura silẹ di ọjọ ipenija nla.

“Agbeyẹwo yoo tun pada waye ninu idajọ ile-ẹjọ agba to sọ Hope Uzodimna di Gomina ipinlẹ Imo. Ko gbọdọ sun asunpiye ko ma ba a ri ipenija loriṣiriṣi. Mi o mọ bo ṣe maa ṣẹlẹ, ṣugbọn nnkan ti mo ri niyẹn. Mo ri i wi pe wọn tako idajọ naa, wọn si ṣe agbeyẹwo rẹ, bẹẹ ni wọn tun yii pada.

“Hope Uzodinma ni lati kiyesara nitori nnkan tiko lero le ṣẹlẹ. O n i lati gbaradi fun agbeyẹwo idajọ ile-ẹjọ agba."


Bẹ o ba gbagbe, ile-ẹjọ agba orilẹ-ede yii lo le oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Emeka Ihedioha ti ajọ INEC ti kọkọ kede rẹ danu, to si kede Uzodinma gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI