Aarẹ orilẹ-ede Mali, Ibrahim Boubacar Keïta ti kọ'we f'ipo rẹ silẹ lojiji. Ori ẹrọ amohunmaworan ni Keïta ti kede ifiposilẹ rẹ lọsan ọjọ Iṣẹgun, Tuside ana.
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii l'awọn ologun digun lọọ gbe Keïta ati olootu ijọba, Boubou Cissé níle agbara wọn, ti wọn si dunkoko mọ wọn pe iṣejọba wọn ti to.
N'igba to n sọrọ, Keïta sọ pe oun ko fẹ itajẹsilẹ kankan ko waye nitori t'oun, idi ni yii toun fi n kede ifiposilẹ oun.
B'awọn ologun ṣe lọ gbe Aarẹ Keïta l'awọn eeyan ti bẹrẹ si i fo fun ayọ, ti wọn si n dunnu kaakiri pe awọn bọ lọwọ ijọba apaṣẹ, nitori pe lati bi oṣu meloo kan l'awọn araalu ti n ṣepade lori bi wọn yoo ṣe yọ Aarẹ wọn kuro.

No comments:
Post a Comment