IDIBO ONDO: MIMIKO TUN JU BỌMBU ỌRỌ NIPA GOMINA AKEREDOLU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 16, 2020

IDIBO ONDO: MIMIKO TUN JU BỌMBU ỌRỌ NIPA GOMINA AKEREDOLU

...Gomina ti ko fẹ ilọsiwaju ni

Gomina ana n'ipinlẹ Ondo, Oluṣẹgun Mimiko ti ṣapejuwe Gomina Rotimi Akeredolu gẹgẹ bi ẹni ti ko nifẹ ilọsiwaju, pẹlu bo ṣe sọ pe o ti pa ẹka eto ilera n'ipinlẹ naa ti.

O ni Gomina ti ko ba ti le ṣe nnkan t'awọn araalu n reti tabi fẹ lati ọwọ ẹ ki i ṣe ẹni to nifẹ ilọsiwaju, ti wọn si gbọdọ gba a danu.

Mimiko lo sọrọ yii lasiko to n gba igbakeji Gomina Akeredolu, Ọgbẹni Agboọla Ajayi to tun ti lọ sinu ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party lati jade dupo gomina ipinlẹ naa lalejo ninu  ile ẹ to wa n'ilu Ondo.


Nibẹ ni Mimiko ti ṣalaye pe aimọye ọrọ lo n gbe inu oun lati sọ nipa ijọba Akeredolu, eyi to ni ko bojumu, paapaa lẹka eto ilera, to si ni asiko ọrọ ko ti i to.


O ni latigba ti Akeredolu ti wa n'ipo naa, ko ti i ṣe idaji awọn iṣẹ akanṣe toun ṣe laarin ọdun mẹrin ijọba oun. Nibẹ lo si ti ni o ti di dandan k'awọn araalu dan ijọba mi in wo, ati pe ki wọn gbaruku ti Ajayi nibi idibo to n bọ lọna lọjọ kẹwaaa oṣu kẹwaa ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI