GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ, ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC BANUJẸ LORI IKÚ GBAJÚMỌ̀ OLÓṢÈLÚ, DÉLÉ SHITTU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 16, 2020

GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ, ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC BANUJẸ LORI IKÚ GBAJÚMỌ̀ OLÓṢÈLÚ, DÉLÉ SHITTU

Lójijì ni ìròyìn ikú gbajugbaja olóṣèlú ìpínlẹ̀ Kwara nnì, Ọnọrebu Ayọdélé Shittu jáde síta, tó sì ba pupọ àwọn èèyàn lọ́kàn jẹ́ káàkiri àgbáyé.
 
Bi iroyin ibanujẹ naa ṣe tẹ Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq lo ti sọ pe nnkan tẹnikẹni ko lero ni, ati pe adanu nla n'iku gbajumọ agba oloṣelu naa jẹ.
 
Igbakeji abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa tẹlẹri ni Oloogbe, Ọnọrebu Dele Shittu jẹ, to si tun jẹ alaga International Vocational, Technical and Entrepreneurship College (IVTEC).

Gomina AbdulRazaq n'igba to n gbe atẹjade ibanikẹdun sita lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye jẹ ko di mimọ pe ki i ṣe pe Oloogbe naa jẹ aṣiwaju t'awọn n bọwọ fun l'asan ninu ẹgbẹ oṣelu APC nikan, o ni gbajugbaja lo jẹ nilu Ọffa pẹlu iwa rere rẹ.

O ni gbogbo ọmọ ilu Ọffa patapata, paapaa awọn mọlẹbi Shittu l'oun ba kẹdun pupọ, to si gbadura pe ki ọlọrun tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere.
 
Bakan naa, ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ naa ṣapejuw oloogbe Shittu gẹgẹ bi ẹni to ti ko ipa ribiribi ninu ẹgbẹ naa, paapaa lori bi ẹgbẹ naa ṣe duro ṣinṣin titi d'asiko yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI