IJỌBA KWARA FUN AWỌN AKẸKỌỌ NI AṢỌ IBOJU-BOMU MARUNDINLAADỌRIN (65,000) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 4, 2020

IJỌBA KWARA FUN AWỌN AKẸKỌỌ NI AṢỌ IBOJU-BOMU MARUNDINLAADỌRIN (65,000)


Bí gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ile-ẹkọ giga pátápátá ní ìpínlẹ̀ Kwara ṣe ń gbìyànjú láti wọlé fun ipalẹmọ idanwo aṣekagba wọn, ijọba ipinlẹ naa ti pese aṣọ iboju-bomu fun gbogbo awọn akẹkọọ lojuna lati dẹkun itankalẹ arun Covid-19.

Ọjọ Aje, Mọnde ana ni ijọba Kwara pin aṣọ iboju-bomu ti ko din ni ẹgbẹrun marundinlaadọrin (65,000) kaakiri ile-ẹkọ fun igbaradi lati wọle wọn lọjọ Wẹside ọla.

Kọmiṣanna fun ọrọ eto ẹkọ n'ipinlẹ naa, Hajia Bisọla Ahmẹd lo tẹwọ gba awọn aṣọ iboju-bomu naa lọwọ igbakeji Gomina, Ọgbẹni Kayọde Alabi.

Alabi nigba to n sọrọ sọ pe lara awọn ileri ijọba lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu lo mu k'ijọba gbe igbesẹ naa, paapaa lasiko ti ajakalẹ arun n fi gbogbo agbaye logbologbo.

Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe ifaara lasan ni aṣọ iboju-bomu t'ijọba pin naa jẹ, nitori pe eyi to ju bẹẹ lọ ṣi n bọ laipẹ, nitori pe gbogbo igba l'awọn yoo maa wa ọna iranlọwọ f'awọn araalu.

O ni yatọ eyi, ijọba ṣi tun maa pin awọn ifọwọ (hand sanitizers) f'awọn akẹkọọ naa, to si ni gbogbo awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ to n ri ọrọ eto ẹkọ ni wọn ti paṣẹ fun pe ki wọn tẹle awọn ilana to le dẹkun itankalẹ arun naa.

Ahmed naa waa dupẹ lọwọ ijọba AbdulRazaq fun akitiyan rẹ lati ri i pe ẹmi ati dukia pẹlu alaafia awọn araalu jẹ oun logun pupọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI