Ẹ GBỌ́ NǸKAN TÍ APC, OYEYẸMI SỌ NÍPA ÌYÀWÓ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ, OLUFỌLAKẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 2, 2020

Ẹ GBỌ́ NǸKAN TÍ APC, OYEYẸMI SỌ NÍPA ÌYÀWÓ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ, OLUFỌLAKẸ


Lonii ni iyawo Gomina ipinlẹ Kwara, Ọmọwe Olufọlakẹ AbdulRazaq n ṣayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹtalelaadọta rẹ, ti gbogbo awọn eeyan jankan-jankan kaakiri agbaye, paapaa awọn ololufẹ rẹ si n ba a yọ, ti wọn n ki ku oriire.

B'awọn eeyan ṣe n ki obinrin naa naa ni ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress, APC ati Kọmiṣanna fun eto iṣuna n'ipinlẹ naa, Arabinrin Oyeyẹmi Ọlasumbọ fi lẹta ikinni ranṣẹ si, nibi ti wọn ti n ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi apẹẹrẹ rere.

Oyeyẹmi ninu ọrọ rẹ ṣapejuwe Olufọlakẹ gẹgẹ bi iya gbogbo eeyan to n kopa ribiribi ninu igbesi aye awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara, paapaa n'ipa ajọ alaanu rẹ, Ajikẹ People's centre.


Siwaju si i lo sọ pe awọn eeyan ipinlẹ naa, paapaa awọn ọdọ at'awọn obinrin ni yooo maa f'ojoojumọ dupẹ lọwọ ẹ, nitori to jẹ idunnu wọn, to si n fa wọn lọwọ s'oke lati kuro ninu iṣẹ ati oṣi.

Ninu ọrọ ẹgbẹ oṣelu APC, wọn ni ti sọ pe ajọ alaanu ti iyawo Gomina da silẹ, iyẹn Ajikẹ foundation ko ṣee fọwọ rọ ti sẹyin ninu awọn ajọ alaanu to n kopa rere laye awọn araalu, paapaa awọn akanda eeyan.

Lẹta naa ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Alaaji Tajudeen Fọlaranmi Aro bu ọwọ lu lo ti sọ pe ṣe ni ajọ naa dabi mọto ireti ayọ f'awọn eeyan, paapaa awọn obinrin, ọmọde n'ipinlẹ naa ati kaakiri Naijiria.

Bẹẹni wọn gbadura funẹmi gigun ati alaafia fun obinrin rere naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI