LẸ́YÌN ỌDÚN MÉJÌ! KASNATY, GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ FẸẸ ṢE ÌRÁNTÍ IKU ÌYÀWÓ Ẹ PẸ̀LÚ AAFA MẸRINDINLOGOJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 5, 2020

LẸ́YÌN ỌDÚN MÉJÌ! KASNATY, GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ FẸẸ ṢE ÌRÁNTÍ IKU ÌYÀWÓ Ẹ PẸ̀LÚ AAFA MẸRINDINLOGOJI


Bọsun Ọlaniyi - Abẹ́òkúta

'Ara mee rírí, mo rí orí ologbo l'atẹ' lorin tí àwọn olólùfẹ́ gbajugbaja sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àgbáyé nnì, Kọlawọle Atanda Adejojo, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Kasnaty-Sugar ń kọ pẹ̀lú bo ṣe sọ pé àwọn àgbààgbà Aafa tí kò dín ni mẹ́rondinlogoji ni yóò jókòó ṣadura níbi ìrántí ọdún méjì tí ìyàwó ẹ, Alaaja Sẹmiat Oyindamọla Adejojo. 

Ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹsàn-án ọdún 2018 ni Alaaja Sẹmiat Abẹkẹ Oyindamọla Adejojo, to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ Semmies' Beauty Place ti wọn ti n ṣe ipara dagbere f'aye lẹyin aisan rampẹ n'ilu Abẹokuta.

Ẹnu ọna abawọle si ile-iwosan ijọba to wa ni Ijaye, Abẹokuta lalẹ ọjọ naa. Bi iroyin yii ṣe jade sita l'awọn ololufẹ Kasnaty ti n ba a kẹdun. Ọjọ keji ni wọn ti sinku ẹ si itẹkuu to wa lagbegbe Olomore.

Bo tilẹ jẹ pe Kasnaty funra rẹ ko ti i ba AWIKONKO sọrọ lori idi pataki to ṣe fẹẹ ṣe iranti naa pẹlu awọn Aafa mẹrindinlogoji (36) fun wakati mẹta gbako, ṣugbọn ohun ti a gbọ ni pe awọn gbajugbaja Aafa oniwaasi lorilẹ-ede yii lo maa wa nibẹ lọjọ naa.

Ileeṣẹ Kasnaty, Adejojo Communication Links pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ Sugarlinks Concept to n ṣagbatẹru Street Voices with Kasnaty naa lo fẹẹ ṣagbatẹru eto adura naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Eto adura naa waye lọdun to kọja, ṣugbọn ọna ti t'ọdun yii fẹẹ gba waye lo n ṣe awọn eeyan ni kayeefi, to si mu k'awọn kan maa sọ pe ifẹ to ni si i lo fa a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI