O PARI! AYEDERU AFỌJU WỌ GAU L'ABAKALIKI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 9, 2020

O PARI! AYEDERU AFỌJU WỌ GAU L'ABAKALIKI

Lilu ko to ibaju lọrọ ri laipẹ yii n'igba ti ọwọ tẹ ayederu afọju kan nilu Abakaliki, ipinlẹ Ebonyi, ẹni ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji ju ko maa tọrọ baara lọ.

Ikorita Union Banki ni wọn sọ pe obinrin ayederu afọju naa maa n jokoo si pẹlu ọmọ rẹ kekere kan to maa n muu kaakiri, nibẹ lo si ti maa n tọrọ owo lọwọ awọn to n kọja lọ.

Amugbalẹgbẹ pataki lori awọn nnkan alumọọni fun Gomina ipinlẹ Ebonyi la gbọ pe aṣiri obinrin naa tu si lọwọ, t'iyẹn si gbe e lọ ọfiisi rẹ, ko to o fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

Rọọbu la gbọ pe obinrin naa maa n fi pa oju rẹ to ba fi fẹẹ lọ tọrọ owo. Iyalẹnu lo si jẹ f'awọn to wa lagbegbe naa, paapaa awọn ti maa n ri obinrin yii n'igba t'aṣiri ẹ pada tu sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI