ONÍṢẸ́ IKÚ Ń KAN ILẸ̀KÙN ASO ROCK L'ABUJA - WÒLÍÌ AYỌDELE TUN JU BỌMBU Ọ̀RỌ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 9, 2020

ONÍṢẸ́ IKÚ Ń KAN ILẸ̀KÙN ASO ROCK L'ABUJA - WÒLÍÌ AYỌDELE TUN JU BỌMBU Ọ̀RỌ̀


Aláṣẹ àti oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual káàkiri àgbáyé, Primate Elijah Ayọdele tí sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ òun lórí ìlera ìyàwó Ààrẹ Muhammadu Buhari, ìyẹn Aisha Buhari tí wá sí ìmúṣẹ.

Primate Elijah Ayọdele sọ pé afi kí àwọn òṣìṣẹ́ Aso Rock, Abuja àtàwọn alatilẹyin Ààrẹ Buhari tètè wá nǹkan ṣe, bí wọn kò bá fẹ́ ẹ fojú sunkún.

O ni a fi kí wọn gbájúmọ́ ọ̀rọ̀ ìlera Ààrẹ Buhari ati ìyàwó rẹ̀, Aisha nítorí pé bí wọn kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, oniṣẹ ikú lo ń kan ilẹ̀kùn fún wọn. 

Ní kété tí Primate Ayọdele tí gbọ pé ara Aisha kò yà gidi, àti pé wọn tí gbé e kúrò ní Nàìjíríà lọ sí Òkè-Òkun lo tí sáré sọ̀rọ̀ náà jáde wí pé àyàfi bí wọn ba tètè gbájúmọ́ ọ̀rọ̀ wọn lo lè mú kí àsọtẹ́lẹ̀ náà má wá sí ìmúṣẹ. 

"Nínú ilé agbára kan náà ṣì ni. Aisha gbọ́dọ̀ là ojú rẹ. Buhari yóò tún padà sunkún bí wọn kò bá ṣọ́ra. Ẹnìkan ṣí tún máa kú nílé agbara. 

"Wọn ní láti gbájúmọ́ ọ̀rọ̀ Ààrẹ àti ìyàwó ẹ dáadáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI