ỌRỌ ẸNU KOBA GOMINA EL-RUFAI, L'AWỌN AGBẸJỌRO BA YẸYẸ RẸ NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 21, 2020

ỌRỌ ẸNU KOBA GOMINA EL-RUFAI, L'AWỌN AGBẸJỌRO BA YẸYẸ RẸ NITA GBANGBA

Itiju nla gba a n'iṣẹlẹ naa jẹ fun Gomina ipinlẹ Kaduna, Malaamu Nasiru El-Rufai nígba ti ẹgbẹ awọn agbẹjọro lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn Nigerian Bar Association (NBA) yẹyẹ rẹ nita gbangba.
 
Ohun ti a gbọ ni pe ipade gbogboogbo kan ni ẹgbẹ awọn agbẹjọro naa fẹẹ ṣe, ti wọn si ti kọwe si Gomina El-Rufai lati wa nibẹ, ki wọn si tun le da a lọla rẹpẹtẹ nibẹ.
 
A gbọ pe Gomina El-Rufai tun jẹ ọkan lara awọn eeyan pataki ti yoo sọrọ nibi eto naa to fẹẹ waye laarin ọjọ kẹrindinlogun si ọjọ kọkandinlọgbọn.

Ori ikanni ayelujara ti Twitter ni ẹgbẹ awọn agbẹjọro ti kede pe awọn ko reti Gomina El-Rufai mọ nibi ipade gbogboogbo wọn, ati pe awọn ko nifẹẹ si i mọ lati wa nibẹ.
 
Ko si nnkan meji to mu ki ẹgbẹ awọn agbẹjọro naa sọrọ yii jade bi ko ṣe ti ọrọ tiwọn loo sọ lori ipaniyan to n ṣẹlẹ l'awọn agbegbe kan n'ipinlẹ Kaduna, eyi ti wọn loo ku diẹ kaato, ti ko si dun mọ awọn agbẹjọro naa ninu.
 
Wọn ni ṣe l'awọn agbẹjọro an jade sita lati fi ẹhonu wọn han si Gomina El-Rufai.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI