OLUDAMỌRAN PATAKI FUN GOMINA KWARA LORI ỌRỌ ILERA KỌWE FIṢẸ SILẸ LOJIJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 21, 2020

OLUDAMỌRAN PATAKI FUN GOMINA KWARA LORI ỌRỌ ILERA KỌWE FIṢẸ SILẸ LOJIJI


Oludamọran pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ eto ilera n'ipinlẹ Kwara, Ọjọgbọn Wale Suleiman tí kọwe fipo rẹ silẹ, Rafiu Ajakaye to jẹ akọwe ìròyìn gómìnà lo f'iroyin náà síta l'Ọjọru, Wẹside àná n'ilu Ilọrin.
 
Wọn ni ọkunrin naa fẹẹ gbajumọ iṣẹ to yan laayo lẹka eto ilera, ko si ni ajọṣepọ to dan mọran laarin awọn ọmọ Naijiria to wa loke-okun.
 
Loju ẹsẹ ni Gomina Abdulrazaq t'ipinlẹ naa tun kede Ọjọgbọn Adekunle David Dunmade lati gba ipo naa, ki iṣẹ si tẹsiwaju lai duro.
 
Bakan naa ni Gomina tun yan ajagun-fẹyinti Saliu Tunde Bello ati Ọgbẹni Aliyu Muyideen gẹgẹ bi oludamọnra pataki ati amugbalẹgbẹ pataki lori ọrọ eto aabo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI