Ẹ WO AWỌN ỌLỌMỌGE TI WỌN N WA ỌKỌ LORI AYELUJARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 27, 2020

Ẹ WO AWỌN ỌLỌMỌGE TI WỌN N WA ỌKỌ LORI AYELUJARA


Yoruba bọ wọn ni airin jinna, ni airi abuke ọkẹrẹ, bi eeyan ba rin jinna, yoo ri ibi ti wn ti n fi odo ibulẹ jẹun.

Rẹgi ni owe yii si ṣe pẹlu bi awọn obinrin ode oni ti ṣe bọ si oju ayelujara lati maa wa ọkọ, ti wọn si gbagbe asa wa to so mọ eto igbeyawo ati alarina.

Kii si ṣe awọn ọlọmọge nikan laa n wi, awọn to ti ṣe igbeyawo to sanpọn ati awọn mii ti ko ri ọkọ gan ko gbẹyin ninu awọn to n wa ọkọ lori ayelujara.

Bi eeyan ba lọ si oju opo Twitter tabi Instagram, to si tẹ ọrọ matchmaking sibẹ, yoo ri pe awọn oju opo alarina tọkọ-taya pọ nibẹ jaburata.

Lọpọ awọn oju opo itakun agbaye wọnyii, awọn obinrin, to fi mọ ọkunrin maa fi iroyin nipa ara wọn, iru ẹsin ti wọn n sin, ati iru ọkọ tabi aya, ti wọn n wa sita.

Diẹ lara awọn oju opo ololufẹ to gbajumọ lori ayelujara nilẹ Naijiria ni matchbybade, halal_matchmaking ati abujamatchmaking.

 

Ki lo n mu awọn obinrin gbe iru igbesẹ yii?

Aṣa Yoruba, lo ni ilana tirẹ nipa ọkọ fifẹ tabi iyawo nini, eyi ti a daye ba.

Bi a ti ṣe jogun ba lọdọ awọn babanla wa, bi ọkunrin ba ri obinrin to wu lọkan, yoo lọ nipasẹ alarina lati kan si awọn obi obinrin naa.

Ojuse alarina si ni lati mọ hulẹ hulẹ nipa itan idile obinrin naa ati iru aisan to n se wọn ninu idile wọn.

Bi ọrọ ba wọ, ohun to kan ni ki wọn ṣe idana, ki igbeyawo si tẹle.

Gẹgẹ bi iwadi ti fi ye wa, lara awọn ohun to n mu ki obinrin maa wa ọkọ lori ayelujara tawọn kan sọ ni iwọnyii:

  • Igbagbọ pe obinrin pọ ju ọkunrin lọ nitori naa ati ri ọkọ ṣoro diẹ
  • Ailootọ awọn ọkunrin naa jẹ idi kan ti awọn obinrin mii fi sọ pe awọn n kan si oju opo lati mọ ẹni ti ko ni ṣaburu fun awọn
  • Airaye ọpọ obinrin ode oni nitori iru iṣẹ ti wọn ṣe
  • Onitiju lawọn obinrin mii ti wọn kii ṣaba ni ọrẹ pupọ
  • Erongba lati fẹ ẹni to niṣẹ lapa, pupọ obinrin ni ko fẹ ọkọ ti ko ni le gbọ bukata wọn, ti eto alarina oju ayelujra yii si fun wọn lanfaani lati wa ẹni to niṣẹ lọwọ.
 
Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI