Ẹ W'OJU HAMISU TO JI MỌTO FRSC GBE L'ABUJA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 6, 2020

Ẹ W'OJU HAMISU TO JI MỌTO FRSC GBE L'ABUJA


Ọdaju paraku ni gendekunrin ti ẹ n wo oju rẹ yii, Hamisu Tukur lorukọ rẹ n jẹ. Ọkan lara awọn mọto ẹṣọ oju popona t'ijọba apapọ, iyẹn FRSC lo ji gbe n'ilu Abuja.

 

Ọwọ ọlọpaa lo pada tẹ ẹ lagbegbe Bwari lasiko to n gbe mọto naa salọ. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja, Anjuguri Manzah lo fi iroyin naa mulẹ laarọ oni wi pe ọwọ ti ba ọmọdun marundinlọgbọn naa, to si ti wa lahamọ awọn.


Inu ṣọọbu igbalode kan to wa ni Wuse Zone 5, iyẹn Sky Memorial Complex ni Hamisu ti lọ ji mọto naa gbe, nibi ti wọn gbe e si l'ana ọjọ Satide.


Manzah ni kete ti wọn ti awọn lolobo l'awọn ti bẹrẹ si i wa mọto naa, ti wọn si pada ri i mọto naa ti wọn pe ni Hilux-HQ-26RS lọwọ ẹ

 

Ileeṣẹ ọlọpaa ti wa gbe awọn nọmba pajawiri wọn sita fun iṣẹlẹ-kiṣẹlẹ to ba n ṣẹlẹ l'awọn agbegbe kaakiri ilu Abuja. Awọn nọmba niwọnyi: 08032003913, 08061581938, 07057337653 ati 08028940883.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI